1 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fi sẹ́nu Jeremáyà láti sọ fún ará ilẹ̀ Bábílónì:
2 “Ẹ sọ ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ sì kéde,kí ẹ sì gbé àṣíà sókè.Ẹ kede, ẹ má sì ṣe bòó wí pé,‘a kó Bábílónì,ojú tí Bélì,a fọ́ Merodákì túútúú,ojú ti àwọn ère rẹ̀,a fọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀ túútúú.’
3 Àwọn ìlú ní apá àríwá yóòsì máa gbógun tì wọ́n.Gbogbo àwọn ènìyàn àti ẹranko ni yóòsá kúrò ní ìlú yìí.
4 “Ní ọjọ́ wọ̀nyí àti ní àkókò náà,”ni Olúwa wí,“Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò jùmọ̀ wá,àwọn, àti àwọn ọmọ Júdà,wọn yóò lọ pẹ̀lú ẹkún láti ṣàfẹ́ri Olúwa Ọlọ́run wọn
5 Wọn ó máa bèèrè ọ̀nà Síhónì, oju wọnyóò sì yí síhà ibẹ̀, wí pé ẹ wá, ẹ jẹ́ kí adarapọ̀ mọ́ Olúwa ní májẹ̀mú ayé-rayé,tí a kì yóò gbàgbé.
6 “Àwọn ènìyàn mi ti jẹ́ àgùntàn tí ó sọnù,àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọn ti jẹ́ kí wọn sìnà,wọ́n ti jẹ́ kí wọn rìn lórí òkèwọ́n ti lọ láti orí òkè ńlá dé òkè kékeré,wọn ti gbàgbé ibùsùn wọn.
7 Gbogbo àwọn tí ó rí wọn, ti pa wọ́n jẹàwọn ọ̀ta wọ́n sì wí pé, ‘Àwa kò jẹ̀binítorí pé wọ́n ti sẹ̀ sí Olúwa ibùgbéòdodo àti ìrètí àwọn baba wọn.’
8 “Jáde kúrò ní Bábílónìfi ilẹ̀ àwọn ará Bábílónì sílẹ̀kí ẹ sì dàbí àgùntàn inú agbo tí à ń kó jẹ̀.
9 Nítorí pé èmi yóò ru,bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò gbé sókè sí Bábílónì àwọn orílẹ̀ èdèńlá láti ilẹ̀ àríwá. Wọn yóò gba àyà wọn lẹ́gbẹ́ rẹ̀;Láti àríwá wá, à ó sì mú ọ. Ọfà wọn yóòdàbí ọfà àwọn akọni alákíkanjú tí wọn kì í wà lọ́wọ́ òfo
10 A ó dààmú Bábílónì, gbogboàwọn tó dààmú rẹ yóò sì múìfẹ́ wọn sẹ,”ni Olúwa wí.
11 “Nítorí pé inú yín dùn nítorí pé ẹ̀yìn yọ̀,ẹ̀yìn olè tí ó jí ìní mi, nítorí tí ẹ̀yìnfi ayọ̀ fò bí ẹgbọ̀rọ̀ màlúù sí koríko tútù,ẹsì ń yan bí akọ-ẹsin.
12 Ojú yóò ti ìyá rẹ, ẹni tí ó bí ọyóò sì gba ìtìjú.Òun ni yóò jẹ́ kékeré jù nínú àwọn orílẹ̀ èdè,ilẹ̀ aṣálẹ̀ àti ihà tí kò lọ́ràá.
13 Nítorí ìbínú Olúwa, kì yóò ní olùgbé;ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú rẹ̀.Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá ni Bábílónì yóòfi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ọgbẹ́ rẹ̀.
14 “Dúró sí àyè rẹ ìwọ Bábílónìàti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ta ọfà náà.Ẹ ta ọfà náà síi, nítorí ó ti sẹ̀ sí Olúwa.
15 Kígbe mọ-ọn ní gbogbo ọ̀nà!Ó tẹríba, òpó rẹ̀ sì yẹ̀,níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ wí pé èyí ni ìgbẹ̀san Olúwa,gbẹ̀san lára rẹ̀.Ṣe síi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmìíràn.
16 Mú kúrò ní Bábílónì olùgbìnàti olùkórè pẹ̀lú ohun ìkórè rẹ̀.Nítorí idà àwọn aninilárajẹ́ kí oníkálùkù padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀,kí oníkálukú sì sá padà sí ilẹ̀ rẹ̀.
17 “A ti fọ́n Ísírẹ́lì ká, Kìnnìún sì ti lé e lọ.Ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ jẹ ẹ́ ni Ọba Ásíríà,ẹni tí ó sì jẹ eegun rẹ̀kẹ́yìn ni Nebukadinésárì Ọba Bábílónì.”
18 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run alágbára Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí;“Ǹ ó fi ìyà jẹ Ọba Bábílónì àti ilẹ̀ rẹ̀gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fìyà jẹ Ọba, Ásíríà.
19 Ṣùgbọ́n, èmi yóò mú Ísírẹ́lìpadà wá pápá oko tútù rẹ̀òun yóò sì máa bọ́ ara rẹ̀ lórí kámẹ̀lì àti Básánì,a ó sì tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ní òkèÉfúráímù àti ní Gílíádì
20 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,”ni Olúwa wí,“À ó wá àìṣedéédé ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì,ṣùgbọ́n a ki yóò rí ìkankan;àti ẹṣẹ Júdà a ki yóò sì rí wọnnítorí èmi yóò dáríjìn àwọn tí ó ṣẹ́kù tí mo dásí.
21 “Kọlu ilẹ̀ Mérátamù àti àwọntí ó ń gbé ní Pékódì.Kọlùú pa á, kí o sì párun pátapáta,”ni Olúwa wí“Ṣe gbogbo ohun tí mo paláṣẹ fún ọ.
22 Ariwo ogun wà ní ilẹ̀ náàìrọ́kẹ̀rẹ̀ ìparun ńlá.
23 Wo bi ilé ayé ti pín sí wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ tó.Wo bí Bábílónì ti di aláìlólùgbéni àárin àwọn orílẹ̀ èdè.
24 Mo dẹ pàkúté sílẹ̀fún ọ ìwọ Bábílónì,kí o sì tó mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀,o ti kó sínú rẹ̀. A mú ọ nítorí pé o tako Olúwa.
25 Olúwa ti kó àwọn ohun èlòìjà rẹ̀ jáde, nítorí pé OlúwaỌlọ́run ọmọ ogun ti ṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ Bábílónì.
26 Ẹ dìde sí láti ilẹ̀ jínjínpárun pátapáta láìṣẹ́kù.
27 Pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́àgùntàn rẹ̀, jẹ́ kí a kówọn lọ ibi tí a ó ti pa wọ́n!Ègbé ní fún wọn! Nítorí ọjọ́ wọn dé,àkókò ìbẹ̀wò wọn.
28 Tẹ́tí sí àwọn tí ó sálọ tí ó sì sálà láti Bábílónì,sì sọ ní Síónì, bí Olúwa Ọlọ́run wa ti gbẹ̀san,ẹ̀san fún tẹ́ḿpílì rẹ̀.
29 “Pe ọ̀pọ̀lopọ̀ ènìyàn, àní gbogbo tafàtafà, sórí Bábílónì,ẹ doti iyikakiri, ma jẹ́ ki ẹnikẹ́ni sálà.Sán fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi gbógbó èyí ti o ti ṣé,ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ síi, nítorí tí ó ti gberagasí Olúwa, sí Ẹni-MÍMỌ̀ Ísirẹ́lì.
30 Nítorí náà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀yóò ṣubú ní ìgboro, a ó sì pa àwọnológun lẹ́nu mọ́,”ní Olúwa wí.
31 “Wò ó, èmi lòdì sí àwọn onígbéraga,”ni Olúwa Ọlọ́run,“ọmọ ogun wí, nítorí ọjọ́ rẹti dé tí ìwọ yóò jìyà.
32 Onígbéraga yóò kọsẹ̀, yóòsì ṣubú, kì yóò sì sí ẹni tí yóò gbé dìde.Èmi yóò tan iná ní ìlú náà,èyí tí yóò sì jo run.”
33 Èyí ni ohun tí Olúwa alágbára sọ:“A pọ́n àwọn ènìyàn Ísírẹ́lìlójú àti àwọn ènìyàn Júdà pẹ̀lú.Gbogbo àwọn tí ó kó wọnnígbèkùn dì í mú ṣinṣinwọn kò sì jẹ́ kí ó sá àsálá.
34 Síbẹ̀, Olùràpadà wọn, Alágbára, Olúwa Ọlọ́run alágbára ni orúkọ rẹ̀.Yóò sì gbe ìjà wa jà,kí ó ba à lè mú wọn wá sinmí ní ilẹ̀ náà;àmọ́ kò sí ìsinmi fún àwọn tí ó ń gbé Bábílónì.
35 “Idà lórí àwọn Bábílónì!”ni Olúwa wí,“lòdì sí àwọn tó ń gbé ní Bábílónì,àwọn aláṣẹ àti àwọn amòye ọkùnrin.
36 Idà lórí àwọn wòlíì èkéwọn yóò di òmùgọ̀! Idà lórí àwọn jagunjagun,wọn yóò sì kún fún ẹ̀rù.
37 Idà lórí àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀àti àwọn àjòjì nínú ẹgbẹ́ rẹ̀.Wọn yóò di obìnrin.Idà lórí àwọn ohun ìṣura rẹ̀!
38 Ilẹ̀ gbígbẹ lórí omi rẹ̀; yóò sì gbẹ.Nítorí pé ó jẹ́ ilẹ̀ àwọn ère,àwọn ère tí yóò ya òmùgọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù.
39 “Nítorí náà àwọn ẹranko ijùpẹ̀lu ọ̀wàwà ni yóò máa gbé ibẹ̀,abo ògòǹgò yóò sì máa gbé inú rẹ̀,a kì ó sì gbé inú rẹ̀ mọ́, láéláé,bẹ́ẹ̀ ni a kì ó ṣàtìpó nínú rẹ̀ láti ìrandíran.
40 Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti gba ìjọbaSódómù àti Gòmóràpẹ̀lú àwọn ìlú agbégbé wọn,”ni Olúwa wí,“kì yóò sí ẹni tí yóò gbé ibẹ̀.
41 “Wò ó! Ọ̀wọ́ ọmọ ogun láti ìhà àríwá;orílẹ̀ èdè ńlá àti àwọn Ọba pípọ̀ ni à ńgbé dìde láti òpin ilẹ̀ ayé.
42 Wọ́n sì di ìhámọ́ra ọ̀kọ̀ àti ọrun,wọ́n burú wọn kò sì ní àánú.Wọ́n bú bí i rírú omi bí wọ́n ti se ń gun ẹsin wọn lọ.Wọ́n wá bí àkójọpọ̀ ogun láti kọlù ọ́, ìwọ ọmọbìnrin Bábílónì.
43 Ọba Bábílónì ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn,ọwọ́ wọn sì rọ,ìrora mú wọn bí obìnrin tí ó ń rọbí.
44 Bí i kìnnìún tí ń bú láti igbó Jọ́dánì.N ó lé Bábílónì kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kánmọ́ kánmọ́.Ta ni ẹni àyànfẹ́ náà tí n ó yàn?Ta ló dàbí mi, ta ló dàbí mi,ta ló sì le dojú ìjà kọmí?”
45 Nítorí náà, gbọ́ ohun tí Olúwa sọ nípa Bábílónìẹni tí ó gbìmọ̀ lòdìsí Bábílónì; n ó sì paagbo ẹran wọn run.
46 Ní dídún fèrè Bábílónìgbogbo ilẹ̀ ayé yóò mì tìtìigbe rẹ̀ yóò sì búja gbogboàwọn orílẹ̀ èdè.