Jeremáyà 18 BMY

Ní Ilé Amọ̀kòkò

1 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremáyà wá wí pe:

2 “Ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀ ni èmi yóò ti bá ọ sọ̀rọ̀.”

3 Nígbà náà ni mo lọ sí ilé amọ̀kòkò mo sì rí i tí ó ń ṣiṣẹ́ kan lórí kẹ̀kẹ́.

4 Ṣùgbọ́n ìkòkò tí ó ń mọ láti ara amọ̀ bàjẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀, nítorí náà ni amọ̀kòkò fi ṣe ìkòkò mìíràn, ó mọ ọ́n bí èyí tí ó dára jù ní ojú rẹ̀.

5 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé:

6 “Ẹyin ilé Ísírẹ́lì, èmi kò ha lè ṣe fún un yín gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe?” ni Olúwa wí. “Gẹ́gẹ́ bí amọ̀ ní ọwọ́ amọ̀kòkò bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin rí ní ọwọ́ mi, ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì.

7 Bí ó bá jẹ́ ìgbà kan, tí èmi kéde kí orílẹ̀ èdè tàbí ìjọba kan di fífà tu láti dojúdé àti láti parun.

8 Tí orílẹ̀ èdè ti mo kìlọ̀ fún bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú wọn, nígbà náà ni Èmi yóò yí ọkàn mi padà níbi àjálù tí mo ti rò láti ṣe sí wọn.

9 Ní ìgbà mìíràn tí èmi bá tún kéde láti tẹ̀dó tàbí gbin orílẹ̀ èdè kan tàbí ìjọba kan.

10 Tí ó sì ṣe búburú ní ojú mi, tí kò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, nígbà náà ni èmi yóò tún ṣe rere tí mo ti fẹ́ ṣe fún wọn.

11 “Ǹjẹ́ nísìnsìnyìí, sọ fún àwọn ènìyàn Júdà àti àwọn olúgbé Jérúsálẹ́mù wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa wí: Wò ó! Èmi ń gbérò ibi sí yin, èmi sì ń ṣe ìpinnu kan lórí yín. Nítorí náà ẹ yípadà kúrò lọ́nà búburú yín kí olúkúlúkù yín sì tún ọ̀nà àti ìṣe rè ṣe.’

12 Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Kò se nǹkànkan, àwa yóò tẹ̀ṣíwájú nínú èrò wa, ẹnìkọ̀ọkan wa, yóò tẹ̀lé agídí ọkàn búburú rẹ̀.’ ”

13 Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí:“Ẹ bèèrè nínú orílẹ̀ èdè, ẹni tíó bá ti gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí ri?Ohun tí ó burú gidi ni wúndíá Ísírẹ́lì ti ṣe.

14 Ǹjẹ́ omi ojo rírí Lébánónì yóò diàwátì láti ibi àpáta? Sí omi tútùtí ó jìnnà sí orísun rẹ yóò kọ̀ láti ṣàn bí?

15 Síbẹ̀ ni àwọn ènìyàn mi ti gbàgbé mi,wọ́n sun tùràrí fún òrìṣà aṣántí ó mú wọn kọsẹ̀ ní ọ̀nà wọn àti ọ̀nà wọn àtijọ́.Wọ́n mú wọn rìn ní ọ̀nà àtijọ́ àti ní ojú tí a kò kọ́

16 Ilẹ̀ wọn yóò wà lásán yóò sì dinǹkan ẹ̀gàn títí láé. Gbogboàwọn tí ó ń kọjá yóò bẹ̀rù, wọnyóò sì mi orí wọn.

17 Gẹ́gẹ́ bí afẹ́fẹ́ láti ìlà oorùn,Èmi yóò tú wọn ká lójú àwọn ọ̀tá wọn.Èmi yóò sì kọ ẹ̀yìn sí wọn, n kì yóò kọjú sí wọnní ọjọ́ àjálù wọn.”

18 Wọ́n sọ wí pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ ṣọ̀tẹ̀ sí Jeremáyà, nítorí òfin ikọ́ni láti ẹnu àwọn àlùfáà kì yóò já sí asán, tàbí ìmọ̀ràn fún àwọn ọlọ́gbọ́n tàbí ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì. Nítorí náà wá, ẹ jẹ́ kí a kọlùú pẹ̀lú ahọ́n wa, kí a má sì ṣe tẹ́tí sí ohun kóhun tí ó bá sọ.”

19 Dẹtí sí ọ̀rọ̀ mi Olúwa, gbọ́ ohuntí àwọn tí ó fi mí sùn ń sọ.

20 Ṣe kí a fi rere san búburú?Síbẹ̀ wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún mi,rántí pé mo dúró níwájú rẹ,mo sì sọ̀rọ̀ ní torí wọn, látiyí ìbínú rẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.

21 Nítorí náà, jẹ́ kí ìyàn mú ọmọ wọnjọ̀wọ́ wọn fún ọwọ́ idàjẹ́ kí ìyàwó wọn aláìlọ́mọ àti opójẹ́ kí a pa àwọn ọkùnrin wọnkí a sì fi idà pa àwọn ọdọ́mọkùnrinwọn lójú ogun.

22 Jẹ́ kí a gbọ́ ohùn ẹkún láti ilé wọnnígbà tí ó bá mu àwọn jagunjagunkọ lù wọ́n lójijì nítorí wọ́n ti gbẹ́kòtò láti mú mi. Wọ́n ti dẹ ìkẹkùn fún ẹṣẹ̀ mi

23 Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa mọ gbogboète wọn láti pa mí, má ṣe fojú fòibi wọn tàbí pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúròlójú rẹ. Jẹ́ kí a mú wọn kúrò níwájú rẹbá wọn jà nígbà ìbínú rẹ.