1 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremáyà wòlíì wá nípa:Àwọn orílẹ̀ èdè:
2 Nípa Éjíbítì,Èyí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ ogun Fáráò Nékò Ọba Éjíbítì ẹni tí a borí rẹ̀ ní Káṣímísì, ní odò Ẹ́fúrétà láti ọwọ́ Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ní ọdún kẹrin Jéhóáíkímù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà:
3 “Pèsè ọ̀kọ̀ rẹ sílẹ̀, èyí tí ó tóbi, àti èyí tí ó kéré, kí o sì yan lọ síta fún ogun!
4 Di ẹṣin ní gàárì,kí ẹ sì gùn ún.Ẹ dúró lẹ́sẹsẹpẹ́lú àsíborí yín!Ẹ dán ọ̀kọ̀ wò,kí ẹ sì wọ ẹ̀wù irin.
5 Kí ni nǹkan tí mo tún rí?Wọ́n bẹ̀rù,wọ́n sì ń padà sẹ́yìn,wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn jagunjagun.Wọ́n sá,wọn kò sì bojú wẹ̀yìn,ìbẹ̀rù sì wà níbi gbogbo,”ni Olúwa wí.
6 “Ẹni tí ó yára kì yóò le sálọ,tàbí alágbára kò ní lè sá àsálà.Ní Gúṣù ní ibi odò Ẹ́fúrétàwọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.
7 “Ta ni èyí tí ó gòkè wá bí odò Náílì,tí omi rẹ̀ ń ru gẹ́gẹ́ bí odò wọ̀n ọn nì?
8 Éjíbítì dìde bí odò náà,bí omi odò tí ń ru.Ó sì wí pé, ‘Èmi yóò dìde, n ó sì bo gbogbo ilẹ̀ ayé.’Èmi yóò pa orílẹ̀ èdè àti àwọn ènìyàn rẹ̀ run.
9 Ẹ gòkè wá ẹ̀yin ẹṣin,ẹ sì sáré kíkankíkan ẹ̀yin kẹ̀kẹ́.Kí àwọn alágbára túbọ̀ tẹ̀síwájú,ẹ̀yin ọkùnrin Kúṣì àti Pútì tí ń gbé ọ̀kọ̀;àti ẹ̀yin ọkùnrin Lìdíà tí ń fa ọrun.
10 Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà jẹ́ ti Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,ọjọ́ ìgbẹ̀san, ìgbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.Idà yóò sì jẹ́ títí yóò fi ní ìtẹ́lọ́rùn,títí yóò fi pa òrùngbẹ rẹ̀ rẹ́ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun yóò rúbọní ilẹ̀ Gúṣù ní odò Ẹ́fúrétà.
11 “Gòkè lọ sí Gílíádì, kí o sì mú ìkunra,ìwọ wúndíá Éjíbítì.Ṣùgbọ́n ní asán ni ìwọ ń lo oògùn,kì yóò sí ìwòsàn fún ọ.
12 Àwọn orílẹ̀ èdè yóò gbọ́ nípa ìtìjú rẹ,igbe rẹ yóò kún gbogbo ayé.Jagunjagun yóò máa ṣubú lu ara wọn lórí rẹ,àwọn méjèèjì yóò sì dìjọ ṣubú papọ̀.”
13 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó bá Jeremáyà wòlíì nì sọ nípa wíwá Nebukadinésárì Ọba Bábílónì láti lọ dojú ìjà kọ Éjíbítì:
14 “Kéde èyí ní Éjíbítì, sì sọ ọ́ ní Nígídò,sọ ọ́ ní Mémífísì àti Táfánésì:‘Dúró sí àyè rẹ kí o sì múra sílẹ̀,nítorí pé idà náà ń pa àwọn tí ó yí ọ ká.’
15 Èéṣe tí àwọn akọni rẹ fi ṣubú?Wọn kò ní le dìde dúró, nítorí Olúwa yóò tì wọ́n ṣubú.
16 Wọn yóò máa ṣubú léralérawọn yóò máa ṣubú lu ara wọn.Wọn yóò sọ wí pé, ‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a padàsí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wa àti ilẹ̀ ìbí wa,kúrò níbi idà àwọn aninilára.’
17 Níbẹ̀ ni wọn ó kígbe pé,‘Ariwo lásán ni Fáráò Ọba Éjíbítì pa,ó ti sọ àǹfààní rẹ̀ nù.’
18 “Bí èmi ti wà láàyè,” ni Ọba,ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ ogun wí pé,“nítòótọ́ gẹ́gẹ́ bí Tábórì láàrin àwọn òkè àtigẹ́gẹ́ bi Kámẹ́lì lẹ́bàá òkun bẹ́ẹ̀ ni òun yóò dé.
19 Iwọ, ọmọbìnrin ti ń gbé Éjíbítì pèsèohun èlò ìrìn-àjò fún ara rẹnítorí Nófù yóò di ahoro a ó sì fi jóná,láìní olùgbé.
20 “Ẹgbọ̀rọ̀ abo màlúù tó lẹ́wà ní Éjíbítìṣùgbọ́n eṣinṣintí yóò le ń bọ̀ láti àríwá.
21 Àwọn jagunjagun rẹ̀dàbí àbọ́pa màlúù.Àwọn pẹ̀lú yóò yípadà,wọn ó sì jùmọ̀ sá,wọn kò ní le dúró,Nítorí tí ọjọ́ ibi ńbọ̀ lórí wọnàsìkò láti jẹ wọ́n níyà.
22 Éjíbítì yóò pòṣé bí ejò tí ń sábí ọmọ ogun ṣe ń tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú agbára.Wọn ó tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú àáké,gẹ́gẹ́ bí i ti agégi.
23 Wọn o gé igbó rẹ̀ lulẹ̀,”ni Olúwa wí,“nítorí ti a kò le rídìí rẹ̀,nítorí pé wọ́n pọ̀ ju elẹ́ǹgà lọ, wọ́n sì jẹ́ àìníye.
24 A ó dójú ti ọmọbìnrin Éjíbítì,a ó fà á lé ọwọ́ àwọn ènìyàn àríwá.”
25 Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé: “Èmi ṣetán láti fi ìyà jẹ Ámónì, òrìṣà Tíbísì, Fáráò Éjíbítì àti àwọn òrìṣà rẹ̀ àti àwọn Ọba rẹ̀ àti àwọn tó gbẹ́kẹ̀lé Fáráò.
26 Èmi ó sì fi wọ́n lé àwọn tó wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́, lé Nebukadinésárì Ọba Bábílónì, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Éjíbítì yóò sì di gbígbé bí i ti àtijọ́,” ni Olúwa wí.
27 “Má bẹ̀rù, ìwọ Jákọ́bù ìránṣẹ́ mi,má fòyà, ìwọ Ísírẹ́lì.Dájúdájú èmi ó gbà ọ́ láti ọ̀nà jínjìn,àwọn ọmọ ọmọ rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn.Jákọ́bù yóò tún ní àlàáfíà àti ààbò,kò sì sí ẹni tí yóò dẹ́rù bà á.
28 Má bẹ̀rù, Jákọ́bù ìránṣẹ́ mi,nítorí pé mo wà pẹ̀lú rẹ,” bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.“Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀ èdè run,láàrin àwọn tí mo fọ́n yín ká sí.Èmi kò ní run yín tán.Èmi yóò jẹ ọ́ níyà lórí òdodo,èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀ láìjẹ ọ́ níyà.”