1 Nígbà tí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìjọba àti àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ Ọba tí ó jọba lé lórí ń bá Jérúsálẹ́mù jà, àti gbogbo àwọn ìlú tí ó yí ká, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa pé:
2 “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì ọmọ ogun wí: Lọ sí ọ̀dọ̀ Sedekáyà Ọba Júdà kí o sì sọ fún-un pé, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Èmi fẹ́ fa orílẹ̀ èdè yìí lé Ọba Bábílónì lọ́wọ́, yóò sì jó palẹ̀.
3 Ìwọ kò ní sá àsálà, ṣùgbọ́n à ó mú ọ, bẹ́ẹ̀ ni a ó sì fà ọ́ lé e lọ́wọ́. Ìwọ yóò rí Ọba Bábílónì pẹ̀lú ojú ara rẹ; yóò sì bá ọ sọ̀rọ̀ lójúkojú; ìwọ yóò sì lọ sí Bábílónì.
4 “ ‘Síbẹ̀, gbọ́ ìlérí Olúwa, ìwọ Sedekáyà Ọba Júdà. Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí nípa rẹ; ìwọ kì yóò ti ipa idà kú;
5 Ìwọ yóò kú ní àlàáfíà. Bí àwọn ènìyàn sì ti ń ṣe iná ìsìnkú ní ọlá fún àwọn baba rẹ, Ọba tí ó jẹ ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò ṣe iná ní ọlá rẹ, wọn ó sì pohùnréré pé, “Yé, olúwa!” Èmi fúnra mi ni ó ṣèlérí yìí ni Olúwa wí.’ ”
6 Nígbà náà ni Jeremáyà wòlíì sọ gbogbo nǹkan yìí fún Sedekáyà Ọba Júdà ní Jérúsálẹ́mù.
7 Nígbà tí ogun Ọba Bábílónì ń bá Jérúsálẹ́mù jà, àti gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tí ó kù ní Júdà, Lákíṣì, Ásékà; àwọn nìkan ni ìlú olódi tí ó kù ní Júdà.
8 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremáyà wá lẹ́yìn ìgbà tí Ọba Sedekáyà ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn ní Jérúsálẹ́mù láti polongo ìtúsílẹ̀ fún àwọn ẹrú.
9 Kí oníkálùkù lè jẹ́ kí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin tí í ṣe Hébérù lọ lọ́fẹ̀ẹ́, kí ẹnikẹ́ni kí ó má mú ará Júdà arákùnrin rẹ̀ sìn.
10 Nítorí náà, gbogbo àwọn aláṣẹ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ọwọ́ sí májẹ̀mú náà láti dá ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin sílẹ̀ kí wọ́n sì má ṣe fi wọ́n sínú ìgbékùn mọ́. Wọ́n sì gbà, wọ́n sì jẹ́ kí wọn lọ lọ́fẹ̀ẹ́
11 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, wọ́n yí ọkàn wọn padà; wọ́n sì mú àwọn ẹrú tí wọ́n ti dá sílẹ̀ padà láti tún máa sìn wọ́n.
12 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá wí pé:
13 “Èyí ni ohun tí Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé: Mo dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín nígbà tí mo mú wọn kúrò ní Éjíbítì; kúrò ní oko ẹrú. Mo wí pé,
14 ‘Ní ọdún keje, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ tú àwọn Hébérù tí wọ́n ti ta ara wọn fún un yín sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti sìn yín fún ọdún mẹ́fà. Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ kí wọn kí ó lọ’; ṣùgbọ́n àwọn baba yín kò gbọ́; bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sími.
15 Láìpẹ́ yìí ẹ ti ronúpìwàdà, ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sì ṣe ìtúsílẹ̀ fún àwọn ènìyàn. Ẹ sì tún bá mi dá májẹ̀mú ní àwọn ilé tí a ti ń pe orúkọ mi.
16 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yípadà, ẹ sì sọ orúkọ mi di èérí, olúkúlùkù sì mú kí àwọn ẹni rẹ tí ó ti sọ di òmìnira bí ọkàn wọn ti fẹ́ padà; ẹ̀yin sì tún fi wọ́n ṣe ẹrú.
17 “Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí: Ẹ̀yin kò fetí sími nípa ọ̀rọ̀ òmìnira láàrin ẹ̀gbọ́n sí àbúrò, láàrin ẹnìkan sí èkejì rẹ̀. Wò ó, èmi yóò kéde òmìnira fún un yín ni Olúwa wí. Sí idà, sí àjàkálẹ̀-àrùn, àti sí ìyàn, èmi ó sì fi yín fún ìwọ̀sí ní gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé.
18 Èmi ó ṣe àwọn ọkùnrin náà tí ó da májẹ̀mú mi, tí kò tẹ̀lé májẹ̀mú tí wọ́n ti dá níwájú mi bí ẹgbọ̀rọ màlúù tí wọ́n gé sí méjì, tí ó sì kọjá láàrin ìpín méjì náà.
19 Àwọn ìjòyè Júdà àti àwọn ti Jérúsálẹ́mù, àwọn aláṣẹ àti àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà tí ó kọjá láàrin àwọn ìpín méjèèjì náà.
20 Èmi ó fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn ọ̀ta wọn, àti lé àwọn tí ń wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́. Òkú wọn yóò jẹ́ oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún àwọn ẹranko ìgbẹ́.
21 “Sédékáyà Ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ ní Júdà ni èmí yóò fi lé àwọn ọ̀ta wọn lọ́wọ́, àti àwọn tí ń wá ẹ̀mí wọn àti lé ọwọ́ ogun Bábílónì tí ó ti lọ kúrò lọ́dọ̀ yín.
22 Wò ó èmi ó pàṣẹ ni Olúwa wí, èmi ó sì mú wọn padà sí ìlú yìí, wọn ó sì baà jà, wọn ó sì kóo, wọn ó fi iná jóo. Èmi ó sì sọ ìlú Júdà dí ahoro.”