1 Nígbà tí Jeremáyà párí sísọ ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rán an sí wọn tan.
2 Ásáríyà ọmọ Hòsáyà àti Jóhánánì ọmọ Káréà, àti gbogbo àwọn agbéraga ọkùnrin sọ fún Jeremáyà pé, “Irọ́ ló ń pa! Olúwa Ọlọ́run wa kò rán ọ láti sọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ sí Éjíbítì láti tẹ̀dó síbẹ̀.’
3 Ṣùgbọ́n Bárúkù ọmọ Néríà ń kó sí ọ lọ́kàn sí wa láti fàwá lé Bábílónì lọ́wọ́, kí wọn le pa wá tàbí kó wa sí ìgbékùn Bábílónì.”
4 Nítorí náà, Jóhánánì ti Káréà àti àwọn ọ̀gágun, àti gbogbo àwọn ènìyàn tàpá sí àṣẹ Olúwa nípa dídúró sí Júdà.
5 Dípò bẹ́ẹ̀, Jóhánánì ọmọ Káréà àti àwọn ọ̀gágun sì ko àwọn àjẹkù Júdà tí wọ́n wá láti gbé ilẹ̀ Júdà láti orílẹ̀-èdè gbogbo tí wọ́n ti tú wọn ká.
6 Wọ́n tún kó àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, àti àwọn ọmọ Ọba tí ó jẹ́ obìnrin èyí tí Nebusàrádánì tí ó jẹ́ adarí ogun ọ̀wọ́ tí ó jẹ́ olùsọ́ ti fi sílẹ̀ pẹ̀lú Jedaháyà ọmọ Élíkámù, ọmọ Sáfánì, àti Jeremáyà wòlíì náà àti Bárúkù ọmọ Néríà.
7 Nítorí náà, wọn wọ Éjíbítì pẹ̀lú àìgbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa, wọ́n sì lọ títí dé Táfánésì.
8 Ní Táfánésì ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá:
9 “Nígbà tí àwọn Júù ń wòye mú àwọn òkúta pẹ̀lú rẹ, kí o sì rì wọ́n mọ́ inú amọ̀ tí ó wà nínú bíríkì tí ó wà níbi pèpéle ẹnu ọ̀nà ààfin Fáráò ní Táfánésì.
10 Báyìí kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run alágbára, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Èmi yóò ránsẹ́ sí ìránṣẹ́ mi Nebukadinésárì Ọba Bábílónì Èmi yóò gbé ìjọba rẹ̀ ka orí àwọn òkúta; èyí tí mo ti rì sí ibí yìí, yóò tan ìjọba rẹ̀ jù wọ́n lọ.
11 Yóò gbé ogun sí Éjíbítì; yóò mú ikú bá àwọn tí ó yan ikú; ìgbèkùn fún àwọn tí ó ti yan ìgbèkùn, àti idà fún àwọn tí ó yan idà.
12 Yóò dá, iná sun Tẹ́ḿpìlì àwọn òrìṣà Éjíbítì, yóò sun Tẹ́ḿpìlì àwọn òrìṣà Éjíbítì, yóò sì mú wọn lọ ìgbèkùn. Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn, yóò ró aṣọ rẹ̀ mọ́ra, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò ró Éjíbítì òun yóò sì lọ kúrò níbẹ̀ ní àlàáfíà
13 Ní Tẹ́ḿpìlì ni yóò ti fọ́ ère ilé òòrùn tí ó wà ní ilẹ̀ Ìjíbítì túútúú, yóò sì sun àwọn Tẹ́ḿpìlì àwọn òrìṣà Éjíbítì.’ ”