Jeremáyà 28 BMY

Hananáyà Wòlíì Èké

1 Ní oṣù karùn ún ní ọdún kan náà, ọdún kẹrin ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba Sedekáyà Ọba Júdà, wòlíì Hananáyà ọmọ Ásúrì, tí ó wá láti Gíbíónì, sọ fún mi ní ilé Olúwa tí ó wà ní iwájú àwọn àlùfáà àti gbogbo ènìyàn:

2 “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Èmi yóò mú àjàgà Ọba Bábílónì rọrùn.

3 Láàrin ọdún méjì, mà á mú gbogbo ohun èlò tí Ọba Nebukadinésárì; Ọba Bábílónì kó kúrò ní ilé Olúwa tí ó sì kó lọ sí Bábílónì padà wá.

4 Èmi á tún mú àyè Jéhóíákínì ọmọ Jéhóíákímù Ọba Júdà padà, àti gbogbo àwọn tí ń ṣe àtìpó láti Júdà ní Bábílónì,’ èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa pé, ‘àjàgà yín láti ọwọ́ Ọba Bábílónì yóò rọrùn.’ ”

5 Wòlíì Jeremáyà fún wòlíì Hananáyà lésì ní iwájú ọmọ àlùfáà àti àwọn ènìyàn tí wọ́n dúró ní ilé Olúwa.

6 Ó sọ wí pé, “Àmín! Kí Olúwa ó ṣe bẹ́ẹ̀! Kí Olúwa ó mú àwíṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ohun èlò ilé Olúwa àti gbogbo àwọn aṣàtìpó padà sí ilẹ̀ Bábílónì.

7 Nísinsìnyìí, tẹ́tí sí àwọn ohun tí mo sọ fún gbígbọ́ àti fún gbígbọ́ gbogbo ènìyàn.

8 Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn wòlíì tí ó ṣáájú rẹ àti èmi ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ogun, ibi àti àjàkálẹ̀ sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè.

9 Ṣùgbọ́n, àwọn wòlíì tí ó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àlàáfíà ni a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì olótítọ́ tí Olúwa rán, tí àṣọtẹ́lẹ̀ rẹ bá wá sí ìmúṣẹ.”

10 Wòlíì Hananáyà gbé àjàgà ọrùn wòlíì Jeremáyà kúrò, ó sì fọ́ ọ.

11 Ó sọ níwájú gbogbo ènìyàn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Bákan náà ni mà á fọ́ àjàgà ọrùn Nebukadinésárì, Ọba Bábílónì láàrin ọdún méjì.’ ” Jeremáyà sì bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ.

12 Láìpẹ́ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wòlíì wá lẹ́yìn ìgbà tí wòlíì Hananáyà ti gbé àjàgà kúrò ní ọrùn wòlíì Jeremáyà wí pé:

13 “Lọ sọ fún Hananáyà, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Ìwọ ti wó àjàgà onígi, ṣùgbọ́n ní àyè wọn, wà á bá àjàgà onírin.

14 Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: mà á fi àjàgà onírin sí ọrùn gbogbo orílẹ̀ èdè láti lè máa sin Nebukadinésárì ti Bábílónì, àti pé gbogbo yín ni ẹ̀ ó máa sìn ín. Mà á tún fún un ní àṣẹ lórí àwọn ẹranko búburú.’ ”

15 Wòlíì Jeremáyà sọ fún Hananáyà wòlíì pé, “Tẹ́tí, Hananáyà! Olúwa ti rán ọ, síbẹ̀, o rọ orílẹ̀ èdè yìí láti gba irọ́ gbọ́.

16 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Mo ṣetán láti mú ọ kúrò nínú ayé, ní ọdún yìí ni ìwọ yóò kú nítorí o ti wàásù ọ̀tẹ̀ sí Olúwa.’ ”

17 Ní oṣù keje ọdún yìí ni Hananáyà wòlíì kú.