Jeremáyà 20 BMY

Jeremáyà Àti Pásúrì

1 Ní ìgbà tí àlùfáà Pásúrì ọmọkùnrin Ímímérì olórí àwọn ìjòyè Tẹ́ḿpìlì Olúwa gbọ́ tí Jeremáyà ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nǹkan wọ̀nyí.

2 Ó mú kí wọ́n lù ú, kí wọ́n sì fi sínú túbú tí ó wà ní òkè ẹnu ọ̀nà ti Bẹ́ńjámínì ní Tẹ́ḿpìlì Olúwa.

3 Ní ọjọ́ kejì tí Páṣúrì tú u sílẹ̀ nínú túbú, Jeremáyà sì sọ fún un wí pé, “orúkọ Olúwa kì í ṣe Páṣúrì fún ọ bí kò ṣe ohun ẹ̀rù.

4 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ. Èmi yóò mú ọ di ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ sí ara rẹ àti sí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Ní ojú ara rẹ, ìwọ yóò sì rí tí wọ́n ṣubú nípa idà ọ̀tá wọn. Èmi yóò fi gbogbo àwọn ọ̀tá Júdà lé Ọba Bábílónì lọ́wọ́, òun yóò sì kó wọn lọ sí Bábílónì tàbí kí ó pa wọ́n.

5 Èmi yóò jọ̀wọ́ gbogbo ọrọ̀ inú ìlú yìí fún ọ̀ta wọn. Gbogbo ìní wọ́n gbogbo ọlá Ọba Júdà. Wọn yóò sì ru ìkógun lọ sí Bábílónì.

6 Àti ìwọ Páṣúrì, gbogbo ènìyàn inú ilé rẹ yóò sì lọ ṣe àtìpó ní Bábílónì. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí, tí wọn yóò sì sin ọ́ síbẹ̀, ìwọ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí ìwọ ti sọ àṣọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún.”

Ìráhùn Jeremáyà

7 Olúwa, o tàn mí jẹ́,o sì ṣẹ́gun.Mo di ẹni ẹ̀gàn ní gbogbo ọjọ́,gbogbo ènìyàn fi mí ṣẹlẹ́yà.

8 Nígbàkúgbà tí mo bá sọ̀rọ̀, èmi sì kígbe sítaèmi á sọ nípa ipá àti ìparun.Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Olúwa ti mú àbùkùàti ẹ̀gàn bá mi ni gbogbo ìgbà.

9 Ṣùgbọ́n bí mo bá sọ pé, “Èmi kì yóò dárúkọ rẹtàbí sọ nípa orúkọ rẹ̀ mọ́,ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bẹ bi iná tí ń jó nínú mití a sé nínú egungun miAgara dá mi ní inú minítòótọ́ èmi kò lè ṣe é.

10 Mo gbọ́ sísọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́,ìbẹ̀rù ni ibi gbogboFi í sùn! Jẹ́ kí a fi sùn!Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń dúrókí èmi ṣubú, wọ́n sì ń sọ pé,Bóyá yóò jẹ́ di títàn,nígbà náà ni àwa yóò borí rẹ̀,àwa yóò sì gba ẹ̀san wa lára rẹ̀.”

11 Ṣùgbọ́n Olúwa wà pẹ̀lú mi gẹ́gẹ́ bí jagunjagun alágbára.Nítorí náà, àwọn tí ó ń lépa mi yóò kọsẹ̀,wọn kì yóò sì borí.Wọn yóò kùnà, wọn yóò sì gba ìtìjú púpọ̀.Àbùkù wọn kì yóò sì di ohun ìgbàgbé.

12 Olúwa alágbára, ìwọ tí ó ń dán olódodo pípé wòtí o sì ń ṣe àyẹ̀wò ọkàn àti ẹ̀yà fínní-fínní,jẹ́ kí èmi kí ó rí ìgbẹ̀san rẹ lórí wọn,nítorí ìwọ ni mo gbé ara mi lé.

13 Kọrin sí Olúwa!Fi ìyìn fún Olúwa!Ó gba ẹ̀mí àwọn aláìnílọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.

14 Ègbé ni fún ọjọ́ tí a bí mi!Kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má ṣe di ti ìbùkún.

15 Ègbé ni fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún baba mi,Tí ó mú kí ó yọ̀, tí ó sì sọ wí pé,“A bí ọmọ kan fún ọ—ọmọkùnrin!”

16 Kí ọkùnrin náà dàbí ìlútí Olúwa gbàkóso lọ́wọ́ rẹ̀ láìkáànúKí o sì gbọ́ ariwo ọ̀fọ̀ ní àárọ̀,ariwo ogun ní ọ̀sán.

17 Nítorí kò pa mí nínú,kí ìyá mi sì dàbí títóbi ibojì mi,kí ikùn rẹ̀ sì di títí láé.

18 Èéṣe tí mo jáde nínú ikùn,láti rí wàhálà àti ọ̀fọ̀àti láti parí ayé mi nínú ìtìjú?