1 Gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ fún yín ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì.
2 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Má se tọ ọ̀nà àwọn orílẹ̀ èdètàbí kí ẹ jẹ́ kí àmù òfuurufú dààmúyín, nítorí pé wọ́n ń dààmú orílẹ̀ èdè.
3 Nítorí pé asán ni asà àwọn ènìyàn,wọ́n gé igi láti inú igbó, oníṣẹ́-ọnàsì gbẹ́ ẹ pẹ̀lú àáké rẹ̀.
4 Wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe élọ́sọ̀ọ́. Wọ́n fi òòlù kàn án àtièṣo kí ó má ba à ṣubú.
5 Wọ́n nàró bí igi ọ̀pẹ, òrìṣà wọnkò le è ṣọ̀rọ̀. Wọ́n gbọdọ̀ máa gbéwọn nítorí pé wọn kò lè rìn. Má ṣebẹ̀rù wọn; wọn kò le è ṣe ibi kankanbẹ́ẹ̀ ni wọn kò si lè ṣe rere kan.”
6 Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ Olúwa;o tóbi orúkọ rẹ sì tóbi lágbára.
7 Ta ni kò yẹ kí ó bẹ̀rù rẹ Ọba àwọnorílẹ̀ èdè? Nítorí tìrẹ ni, láàrin àwọnọlọ́gbọ́n ènìyàn ní orílẹ̀ èdè àtigbogbo ìjọba wọn, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ.
8 Gbogbo wọn jẹ́ aláìlóye àti òpè, wọ́nń kọ́ ẹ̀kọ́ àwọn ère igi tí kò ní láárí
9 Sílífà tí a ti kàn ni a mú wá látiTásísì, àti wúrà láti Lépásì; èyí tíàwọn onísọ́nà àti alágbẹ̀dẹ ṣe tí wọ́nkùn ní àwọ̀ aró àti eléṣé àlùkò,èyí jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣẹ́.
10 Ṣùgbọ́n Olúwa ni Ọlọ́run tòótọ́,òun ni Ọlọ́run alààyè, Ọba ayérayé.Nígbà tí ó bá bínú, ayé yóò wárìrì;orílẹ̀ èdè kò lè fi ara da ìbínú rẹ̀.
11 “Sọ èyí fún wọn: ‘Àwọn ọlọ́run kékèèké tí kò dá ọ̀run àti ayé ni yóò ṣègbé láti ayé àti ní abẹ́ ọ̀run.’ ”
12 Ọlọ́run dá ayé pẹ̀lú agbára rẹ̀,ó dá àgbáyé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀,ó mú kí ọ̀run kí ó fẹ̀ tóbi síta nípa òye rẹ̀.
13 Nígbà tí ó bá sán àrá, àwọn omilọ́run a sì pariwo, ó mú kí ìkuùkù rusókè láti òpin ayé: ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò,ó sì ń mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀.
14 Gbogbo ènìyàn jẹ́ aláìlóye àti aláìnímọ̀,ojú sì ti gbogbo alágbára pẹ̀lú ère rẹ̀,èrú ni ère rẹ̀, kò sì sí ẹ̀mí nínú wọn.
15 Asán ni wọ́n, iṣẹ́ yẹ̀yẹ́ sì ni;nígbà tí ìdájọ́ wọn bá dé, wọn yóò ṣègbé.
16 Ẹni tí ó bá jẹ́ ìpín Jákọ́bù kò sìdàbí èyí, nítorí òun ni ó ṣẹ̀dáohun gbogbo àti Ísírẹ́lì tí ó jẹ́ẹ̀yà ìjogún rẹ̀. Olúwa àwọn ọmọogun ni orúkọ rẹ̀.
17 Kó ẹrù rẹ kúrò láti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀ìwọ tí o ń gbé ní abẹ́ ààbò.
18 Nítorí èyí ni Olúwa wí:“Ní àkókò yìí,èmi yóò gbọn àwọn tí ó ń gbéilẹ̀ náà jáde. Èmi yóò mú ìpọ́njúbá wọn, kí wọn kí ó lè rí wọn mú.”
19 Ègbé ni fún mi nítorí ìpalára mi!Ọgbẹ́ mi jẹ́ èyí tí kò lè sàn, bẹ́ẹ̀ nimọ sọ fún ara mi,“Èyí ni àìsàn mi, mo sì gbọdọ̀ fi orí tì í.”
20 Àgọ́ mi bàjẹ́, gbogbo okùn rẹ̀ sì já.Àwọn ọmọ mi ti lọ lọ́dọ̀ mi, wọn kò sì sí mọ́Kò sí ẹnìkankan pẹ̀lú mi mọ́, báyìí kò sí ẹni tí yóòná àgọ́ mi tàbí ṣe ibùgbé fún mi
21 Àwọn olùsọ́ àgùntàn jẹ́ aláìlóye, wọnkò sì wá Olúwa: nítorí náà wọn kì yóòṣe rere àti pé gbogbo agbo wọn ni yóò túká.
22 Fetísílẹ̀; ariwo ìdàrúdàpọ̀ ńlá náà ń bọ̀láti ilẹ̀ àríwá, yóò sì sọ ìlú Júdà diahoro àti ihò jàkùmọ̀
23 Èmi mọ̀ Olúwa wí pé ayé ènìyàn kì íṣe ti ara rẹ̀, kì í ṣe fún ènìyàn láti gbe igbésẹ ara rẹ̀.
24 Tún mi ṣe Olúwa, pẹ̀lú ìdájọ́ nìkankí o má sì ṣe é nínú ìbínú rẹ. Kí ìwọmá ṣe sọ mí di òfo.
25 Tú ìbínú rẹ síta sórí àwọn orílẹ̀ èdètí kò mọ̀ ọ́, sórí àwọn ènìyàntí wọn kò pe orúkọ rẹ. Nítorí péwọ́n ti jẹ Jákọ́bù run, wọ́n ti jẹ ẹ́run pátapáta, wọ́n sì ti ba ilẹ̀ ibùgbé rẹ̀ jẹ́.