Jeremáyà 27 BMY

Júdà Yóò Sin Nebukadinésárì

1 Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìṣèjọba Sedekáyà ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa:

2 Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Ṣe ìjárá àti àjàgà fún ara rẹ, kí o sì fi wé ọrùn rẹ.

3 Kí o rán ọ̀rọ̀ sí Ọba ti Édómù, Móábù, Ámónì, Tírè àti Sídónì láti ọwọ́ àwọn ikọ̀ tí ó wá sí Jérúsálẹ́mù sọ́dọ̀ Sedekáyà Ọba Júdà.

4 Kí o sì pàṣẹ fún wọn láti wí fún àwọn olúwa wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: “Sọ èyí fún àwọn olúwa rẹ:

5 Pẹ̀lú agbára ńlá mi àti ọwọ́ nínà mi ni Èmi dá ayé, ènìyàn àti ẹranko tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, Mo sì fún ẹni tí ó wu ọkàn mi.

6 Nísinsìn yìí, Èmi yóò fa gbogbo orílẹ̀ èdè rẹ fún Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ìránṣẹ́ mi; Èmi yóò sì mú àwọn ẹranko búburú wọ̀n-ọn-nì jẹ́ tirẹ̀.

7 Gbogbo orílẹ̀ èdè ni yóò máa sìn ín àti àwọn ọmọdọ́mọ rẹ̀ títí ilẹ̀ rẹ yóò fi dé; ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè àti àwọn Ọba ńlá ni yóò tẹríba fún.

8 “ ‘ “Àmọ́ tí orílẹ̀ èdè tàbí ìjọba kan kò bá ní sin Nebukadinésárì Ọba Bábílónì, tàbí kí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní abẹ́ àjàgà rẹ̀; Èmi yóò fi ìyà jẹ orílẹ̀ èdè náà nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn, ni Olúwa wí títí Èmi yóò fi run wọ́n nípa ọwọ́ rẹ̀.

9 Nítorí náà, ẹ má ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí àwọn wòlíì yín, àwọn aláfọ̀ṣẹ yín, àwọn tí ń rọ́ àlá fún un yín, àwọn oṣó yín, tabi àwọn àjẹ́ yín tí wọ́n ń sọ fún un yín pé, ‘Èyin kò ní sin Ọba Bábílónì.’

10 Wọ́n ń sọ àṣọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún un yín èyí tí yóò mú u yín jìnnà réré kúrò ní ilẹ̀ yín; kí Èmi kí ó lè lé yín jáde, kí ẹ̀yin ó sì ṣègbé.

11 Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀ èdè kankan bá tẹ orí rẹ̀ ba lábẹ́ àjàgà Ọba Bábílónì, tí ó sì sìn ín, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀ èdè náà wà lórí ilẹ̀ rẹ̀ láti máa ro ó, àti láti máa gbé ibẹ̀ ni Olúwa wí.” ’ ”

12 Èmi sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún Sedekáyà Ọba Júdà wí pé: “Tẹ orí rẹ ba lábẹ́ àjàgà Ọba Bábílónì, sìn ín ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ yóò sì yè.

13 Kí ló dé tí ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn, èyí tí Olúwa fi ń halẹ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀ èdè tí kò bá sin Ọba Bábílónì?

14 Ẹ má ṣe fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tí ó ń sọ wí pé, ‘Ẹ̀yin kò ní sin Ọba Bábílónì,’ nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ eké ni wọ́n ń sọ fún un yín.

15 ‘Èmi kò rán wọn ni Olúwa wí. Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi. Nítorí náà, Èmi yóò lé wọn, wọn yóò sì ṣègbé, ẹ̀yin pẹ̀lú àwọn wòlíì tí ó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún un yín.’ ”

16 Nígbà náà ni mo sọ fún àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn ènìyàn náà wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: Ẹ má ṣe fetí sí nǹkan tí àwọn wòlíì ń sọ pé, ‘Láìpẹ́ ohun èlò ilé Olúwa ni a ó kó padà láti Bábílónì,’ àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ. Ẹ má tẹ́tí sí wọn.

17 Má ṣe tẹ́tí sí wọn, ẹ máa sin Ọba Bábílónì, ẹ̀yin yóò sì yè. Èéṣe tí ẹ̀yin yóò fi di ìdíbàjẹ́?

18 Tí wọ́n bá jẹ́ wòlíì, tí wọ́n sì ní ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ kí wọ́n bẹ Olúwa kí a má ṣe kó ohun èlò tí ó kù ní ilé Júdà àti Jérúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì.

19 Nítorí pé, èyí ni ohun tí Olúwa sọ nípa àwọn opó, omi òkun níti ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti níti ohun èlò ìyókù tí ó kù ní orílẹ̀ èdè náà.

20 Èyí tí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì kò kó lọ nígbà tí ó mú Jéhóíákímù Ọba Júdà lọ sí ìgbèkùn láti Jérúsálẹ̀mù lọ sí Bábílónì, pẹ̀lú àwọn ọlọ́lá Júdà àti Jérúsálẹ́mù.

21 Lóòótọ́, èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí nípa àwọn ohun ìṣúra tí ó ṣẹ́kù ní ilé Olúwa àti ní ààfin Ọba Júdà àti ní Jérúsálẹ́mù:

22 ‘A ó mú wọn lọ sí ilẹ̀ Bábílónì, ní ibẹ̀ ni wọn ó sì wà títí di ìgbà tí mo bá padà,’ èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa. ‘Lẹ́yìn èyí, mà á mú wọn padà, Èmi yóò sì ṣe wọ́n lọ́jọ̀ ní ibí yìí.’ ”