Jeremáyà 9 BMY

1 Áà! Orí ìbá jẹ́ orísun omi kí ojú mi sì jẹ́ orísun omijéÈmi yóò sì sunkún tọ̀sán tòrunítorí pípa àwọn ènìyàn mi.

2 Áà! èmi ìbá ní ilé àgbàwọ̀ fúnàwọn arìnrìn-àjò ní ihà kí nba à lè fi àwọn ènìyàn mi sílẹ̀kí n sì lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn:nítorí gbogbo wọn jẹ́ pańṣágààjọ aláìsòótọ́ ènìyàn ni wọ́n.

3 Wọ́n ti pèsè ahọ́n wọn sílẹ̀ bí ọfàláti fi pa irọ́; kì í ṣe nípa òótọ́ni wọ́n fi borí ní ilẹ̀ náà. Wọ́n ńlọ láti inú ẹ̀ṣẹ̀ kan sí òmíràn,wọn kò sì náání mi,ní Olúwa wí.

4 Ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ; má ṣegbẹ́kẹ̀lé àwọn arákùnrin rẹnítorí pé oníkálukú arákùnrinjẹ́ atannijẹ, oníkálukú ọ̀rẹ́ sì jẹ́ abanijẹ́.

5 Ọ̀rẹ́ ń dalẹ̀ ọ̀rẹ́. Kò sì sí ẹnitó sọ òótọ́, wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọnláti máa purọ́. Wọ́n sọ ara wọndi onírẹ̀wẹ̀sì pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀

6 Ó ń gbé ní àárin ẹ̀tànwọ́n kọ̀ láti mọ̀ mí nínúẹ̀tàn wọn,ni Olúwa wí.

7 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí:“Wò ó, èmi dán wọn wo; nítorí pékí ni èmi tún le è ṣe? Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi?

8 Ahọ́n wọn dàbí ọfà olóróó ń sọ ẹ̀tàn; oníkálukú sì ńfi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ àlàáfíà síaládúgbò rẹ̀; ní inúọkàn rẹ̀, ó dẹ tàkúté sílẹ̀.

9 Èmi kì yóò háa fi ìyà jẹ wọ́n nítorí èyí?”ni Olúwa wí.“Èmi kì yóò ha gbẹ̀san arami lórí irú orílẹ̀ èdè yìí bí?”

10 Èmi yóò sì sunkún, pohùnréréẹkún fún àwọn òkè; àti ẹkúnìrora lórí pápá oko ihà wọ̀n-ọn-nì.Nítorí wọ́n di ahoro, wọn kò sìkọjá ní ibẹ̀. A kò sì gbọ́ igbeẹran ọ̀sìn, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀runsì ti sá lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹranko sì ti lọ.

11 “Èmi yóò sì sọ Jérúsálẹ́mù di òkìtìàlàpà àti ìhò àwọn ìkokò.Èmi ó sì sọ ìlú Júdà di ahorotí ẹníkẹ́ní kò sì ní le è gbé.”

12 Ta ni ẹni náà tí ó ní ọgbọ́n láti mòye nǹkan wọ̀nyí? Ta ni Olúwa ti sọ èyí fún, tí ó sì lè ṣàlàyé rẹ̀? È é ṣe tí ilẹ̀ náà fi ṣègbé bí ihà, tí ẹnìkankan kò sì le là á kọjá?

13 Olúwa sì wí pé, nítorí pé wọ́n ti kọ òfin mi sílẹ̀, èyí tí mo gbé kalẹ̀ níwájú wọn, wọn ṣe àìgbọ́ràn sí wọn, wọn kò sì rìn nínú òfin mi.

14 Dípò èyí, wọ́n ti tẹ̀lé agídí ọkàn wọn, wọ́n ti tẹ̀lé Báálì gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe kọ́ wọn.

15 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, “Wò ó, Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ oúnjẹ kíkorò àti láti mu omi májèlé.

16 Èmi yóò sì tú wọn ká láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, nínú èyí tí àwọn tàbí àwọn baba wọn kò mọ̀. Èmi yóò sì lépa wọn pẹ̀lú idà títí èmi yóò fi pa wọ́n run.”

17 Èyí sì ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí:“Ṣáà wò ó nísisìnyìí! Ké sí obìnrin ọlọ́fà nì kí ó wá;sì ránsẹ́ pe àwọn tí ó mòye nínú wọn.

18 Jẹ́ kí wọn wá kíákíá,kí wọn wá pohùnréré ẹkúnlé wa lórí títí ojú wa yóòfi ṣàn fún omijé tí omi yóò sì máa ṣàn àwọn ìpéǹpéjú wa

19 A gbọ́ igbe ìpohùnréréẹkún ní Síónì:‘Àwa ti ṣègbé tó!A gbọdọ̀ fi ilẹ̀ wa sílẹ̀,nítorí pé àwọn ilé wa ti parun.’ ”

20 Nísínsìnyìí, ẹ̀yin obìnrin ẹ gbọ́ọ̀rọ̀ Olúwa. Sí etí yín síọ̀rọ̀ ẹnu rẹ. Kọ́ àwọn ọmọbìnrinyín ní ìpohùnréréẹkún, kí ẹ sì kọ́ ara yín ní arò.

21 Ikú ti gba ojú fèrèsé wa wọléó sì ti wọ odi alágbára waó ti ké àwọn ọmọ kúrò níàdúgbò àti àwọn ọ̀dọ́mọ́kùnrinkúrò ní gbọ̀ngàn ìta gbangba.

22 Sọ pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“ ‘Òkú àwọn ènìyàn yóò ṣubúbí ààtàn ní oko gbangbaàti bí ìbùkúnwọ́ lẹ́yìn olùkórèláìsí ẹnìkankan láti kó wọn jọ.’ ”

23 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Má ṣe jẹ́ kí ọlọgbọ́n yangànnítorí ọgbọ́n rẹ̀, tàbí alágbáranítorí rẹ̀, tàbí ọlọ́rọ̀nítorí ọrọ̀ rẹ̀.

24 Ẹ jẹ́ kí ẹni tí ńṣògo nípa èyí nì wí péòun ní òye, òun sì mọ̀míwí pé, Èmi ni Olúwa tí ńṣe òtítọ́ ìdájọ́ àti òdodoní ayé nínú èyí ni mo níinú dídùn sí,” Olúwa wí.

25 “Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí Èmi yóò fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí a kọ ilà fún nínú ara nìkan.

26 Éjíbítì, Júdà, Édómù, Ámónì, Móábù àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní ọ̀nà jínjìn réré ní ihà. Nítorí pé gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí jẹ́ aláìkọlà gbogbo àwọn ará ilé Ísírẹ́lì sì jẹ́ aláìkọlà ọkàn.”