1 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé: “Kódà kí Mósè àti Sámúẹ́lì dúró níwájú mi, ọkàn mi kì yóò lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Mú wọn kúrò níwájú mi! Jẹ́ kí wọn ó lọ!
2 Tí wọ́n bá sì bi ọ́ pé, ‘Níbo ni kí a lọ?’ Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí:“ ‘Àwọn tí a kọ ikú mọ́, sí ikú;àwọn tí a kọ idà mọ́, sí idà;àwọn tí a kọ ìyàn mọ́, sí ìyàn;àwọn tí a kọ ìgbékùn mọ́ sí ìgbékùn.’
3 “Èmi yóò rán oríṣìí ìparun mẹ́rin láti kọlù wọ́n,” ni Olúwa wí, “Idà láti pa, àwọn ajá láti wọ́ wọn lọ, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko orí ilẹ̀ láti jẹ àti láti parun.
4 N ó sọ wọ́n di ẹni ìkórìíra níwájú gbogbo ìjọba ayé torí ohun tí Mánásè ọmọ Heṣekáyà Ọba àwọn Júdà ṣe ní Jérúsálẹ́mù.
5 “Ta ni yóò ṣàánú rẹ, ìwọ Jérúsálẹ́mù?Ta ni yóò dárò rẹ?Ta ni yóò dúró béèrè àlàáfíà rẹ?
6 O ti kọ̀ mí sílẹ̀,” ni Olúwa wí“Ìwọ sì wà nínú ìpadàsẹ́yìn.Nítorí náà, Èmi yóò dáwọ́ lé ọ, èmi ó sì pa ọ́ run;Èmi kò sì ní fi ojú àánú wò ọ́ mọ́.
7 Èmi kò tún lè fi ìfẹ́ hàn si ọÈmi yóò fi atẹ fẹ́ wọn sí ẹnu ọ̀nàìlú náà. Èmi yóò mú ìsọ̀fọ̀ àti ìparunbá àwọn ènìyàn mi nítorí pé wọnkò tíì yí padà kúrò lọ́nà wọn.
8 Èmi yóò jẹ́ kí àwọn opó wọn pọ̀ juyanrìn òkun lọ. Ní ọjọ́kanrí nièmi ó mú apanirun kọlu àwọnìyá ọmọkùnrin wọn. Lójìjì nièmi yóò mú ìfòyà àti ìbẹ̀rù bá wọn.
9 Ìyá ọlọ́mọ méje yóò dákú, yóòsì mí ìmí ìgbẹ̀yìn. Òòrùn rẹyóò wọ̀ lọ́sàn-án gangan, yóòdi ẹni ẹ̀tẹ́ òun àbùkù. Èmiyóò fi àwọn tí ó bá yè wá síwájúàwọn ọ̀tá wọn tí idà wà lọ́wọ́ wọn,”ni Olúwa wí.
10 Áà Ó ṣe tí ìyá mi bí mi:ọkùnrin tí gbogbo ìtẹ́ tiraka tí wọ́nsì bá jà, èmi kò wín ni, bẹ́ẹ̀ nièmi ò yá lọ́wọ́ ẹni síbẹ̀, gbogbo ènìyàn ló ń fi mí ré.
11 Olúwa sọ pé,“Dájúdájú èmi ò dá ọ sí fún ìdí kan pàtó.Dájúdájú mo mú kí àwọn ọ̀tá rẹtẹríba níwájú rẹ nígbà ibi àti ipọ́njú.
12 “Ǹjẹ́ ẹnìkan lè fi ọwọ́ ṣẹ́ irinirin láti àríwá tàbí idẹ?
13 Gbogbo ọlá àti ìṣúra rẹ ni èmió fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun láìgbankànkan nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹjákèjádò orílẹ̀ èdè rẹ.
14 Èmi yóò fi ọ́ ṣẹrú fún àwọn ọ̀tá rẹní ìlú tí ìwọ kò mọ̀ nítorí ìbínúmi yóò rán iná tí yóò jó ọ.”
15 Ó yé ọ, ìwọ Olúwa rántí mi kí osì ṣe ìtọ́jú mi; gbẹ̀san mi láraàwọn tó dìtẹ̀ mi. Ìwọ ti jìyà fúnìgbà pípẹ́, má ṣe mú mi lọ, nínú bímo ṣe jìyà nítorí tìrẹ.
16 Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ dé, mo jẹ wọ́nÀwọn ni ìdùnnú àti ayọ̀ ọkàn miNítorí pé orúkọ rẹ ni a fi ń pè míÌwọ Olúwa Ọlọ́run alágbára.
17 Èmi kò fìgbà kan jókòó láàrin àwọn ẹlẹ́gàn.Má ṣe bá wọn yọ ayọ̀ pọ̀;mo dá jókòó torí pé ọwọ́ rẹ wàlára mi, ìwọ sì ti fi ìbínú rẹ kún inú mi.
18 È é ṣe tí ìrora mi kò lópin, tí ọgbẹ́mi ń nira tí kò sì ṣe é wòsàn?Ṣe ìwọ yóò dàbí kànga ẹ̀tàn sí mi,gẹ́gẹ́ bí ìsun tó kọ̀ tí kò sun?
19 Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí:“Tí o bá ronúpìwàdà, Èmi ó dá ọ padàwá kí o lè máa sìn mí. Tí ó básọ ọ̀rọ̀ tó dára ìwọ yóò di ọ̀gbẹnusọmi. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí kọjú sí ọ;ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọjú sí wọn
20 Èmi fi ọ́ ṣe odi idẹ tí ó lágbárasí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó bá ọ jàṣùgbọ́n, wọn kò ní lè borí rẹnítorí pé, mo wà pẹ̀lú rẹ láti gbà ọ́ là,kí n sì dáàbò bò ọ́,”ni Olúwa wí.
21 “Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọnìkà ènìyàn, Èmi yóò sì rà ọ́padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.”