Jeremáyà 37 BMY

Jeremáyà Nínú Túbú

1 Sedekáyà ọmọ Jòsáyà sì jọba nípò Kóráyà ọmọ Jéhóíákímù ẹni tí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì fi jẹ Ọba ní ilẹ̀ Júdà.

2 Ṣùgbọ́n àti òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà kò fetísí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ nípa wòlíì Jeremáyà.

3 Ṣedekáyà Ọba sì rán Jéhúkálì ọmọ Semeláyà àti Sefanáyà ọmọ Máséyà sí Jeremáyà wòlíì wí pé, “Jọ̀wọ́ gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run wa fún wa.”

4 Nígbà yìí Jeremáyà sì ń wọlé, ó sì ń jáde láàrin àwọn ènìyàn nítorí wọ́n ti fi sínú túbú.

5 Àwọn ọmọ ogun Fáráò ti jáde kúrò nílẹ̀ Éjíbítì àti nígbà tí àwọn ará Bábílónì tó ń ṣàtìpó ní Jérúsálẹ́mù gbọ́ ìròyìn nípa wọn, wọ́n kúrò ní Jérúsálẹ́mù.

6 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Jeremáyà òjíṣẹ́ Ọlọ́run wá:

7 “Èyí ni, ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì sọ fún Ọba àwọn Júdà tó rán ọ láti wádìí nípa mi. ‘Àwọn ọmọ ogun Fáráò tó jáde láti kún ọ lọ́wọ́ yóò padà sílẹ̀ wọn sí Éjíbítì.

8 Nígbà náà ni àwọn ará Bábílónì yóò padà láti gbógun ti ìlú. Wọn yóò mú wọn nígbèkùn, wọn yóò sì fi iná jó ìlú náà kanlẹ̀.’

9 “Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Ẹ má ṣe tan ara yín jẹ ní èrò wí pé, ‘Àwọn ará Bábílónì yóò fi wá sílẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú;’ wọn kò ní ṣe bẹ́ẹ̀.

10 Kódà tó bá ṣe pé wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Bábílónì tí ń gbógun tì yín àti àwọn tí ìjàǹbá ṣe, tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ní ibùdó wọn; wọn yóò jáde láti jó ìlú náà kanlẹ̀.”

11 Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun Bábílónì ti kúrò ní Jérúsálẹ́mù nítorí àwọn ọmọ ogun Fáráò.

12 Jeremáyà múra láti fi ìlú náà sílẹ̀, láti lọ sí olú ìlú Bẹ́ńjámínì láti gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ nínú ohun ìní láàrin àwọn ènìyàn tó wà níbẹ̀.

13 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ẹnu-bodè Bẹ́ńjámínì, olórí àwọn olùṣọ́ tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Íríjà ọmọ Ṣelemáyà ọmọ Hananáyà mú un, ó wí pé, “Ìwọ ń yapa sí àwọn ará Bábílónì.”

14 Jeremáyà sọ wí pé, “Èyí kì í ṣe òtítọ́! Èmi kò yapa sí àwọn ará Bábílónì.” Ṣùgbọ́n Íríjà kọ tí ikún sí i, dípò èyí a mú Jeremáyà, ó sì mú un lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ìjòyè.

15 Wọ́n bínú sí Jeremáyà, wọ́n jẹ ẹ́ níyà, wọ́n tún fi sí àtìmọ́lé nílé Jónátanì akọ̀wé nítorí wọ́n ti fi èyí ṣe ilé túbú.

16 Wọ́n fi Jeremáyà sínú túbú tí ó ṣókùnkùn biribiri; níbi tí ó wà fún ìgbà pípẹ́.

17 Nígbà náà ni Ọba Sedekáyà ránṣẹ́ sí i, tí ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú wá sí ààfin níbi tí ó ti bi í ní ìkọ̀kọ̀ pé, “Ìfẹ́ ọ̀rọ̀ kan wà láti ọ̀dọ̀ Olúwa?”“Bẹ́ẹ̀ ni,” Jeremáyà fèsì pé, “wọn ó fi ọ́ lé ọwọ́ Ọba Bábílónì.”

18 Nígbà náà, Jeremáyà sọ fún Ọba Sedekáyà pé, “Irú ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ yín, àwọn ìjòyè yín pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ẹ fi sọ mí sínú túbú?

19 Níbo ni àwọn wòlíì yín tí wọ́n ń sọ àṣọtẹ́lẹ̀ fún-un yín wí pé Ọba Bábílónì kò ní gbógun tì yín wá?

20 Ṣùgbọ́n ní báyìí, Olúwa mi Ọba jọ̀wọ́ gbọ́. Jẹ́ kí n mú ẹ̀dùn ọkàn mi tọ̀ ọ́ wá; má ṣe rán mi padà sí ilé Jónátanì akọ̀wé, à fi kí n kú síbẹ̀.”

21 Ọba Sedekáyà wá pàṣẹ pé kí wọ́n fi Jeremáyà sínú àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́, àti kí wọn sì fún ní àkàrà ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan títí tí àkàrà yóò fi tán; bẹ́ẹ̀ ni Jeremáyà wà nínú àgbàlá náà.