1 “Tí ìwọ yóò bá padà, Ìwọ Ísírẹ́lìpadà tọ̀ mí wá,”ni Olúwa wí.“Tí ìwọ yóò bá sì mú àwọn òrìṣà tí ìwọ ń ṣe kúrò níwájú mi,tí o kò sì yapa,
2 Tí ó bá jẹ́ lóòtọ́ àti òdodo niìwọ búra. Nítòótọ́ bí Olúwa ti wà láàyè,nígbà náà ni orílẹ̀ èdè yóò di alábùkún fúnnípaṣẹ̀ rẹ àti nínú rẹ̀ ni wọn yóò ṣògo.
3 Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún àwọn ènìyàn Júdà àti Jérúsálẹ́mù.“Hú gbogbo ilẹ̀ tí ẹ kò lò rí,kí o má sì ṣe gbìn sáàrín ẹ̀gún.”
4 Kọ ara rẹ ní ilà sí Olúwakọ ọkàn rẹ ní ilàẹ̀yin ènìyàn Júdà àti gbogbo ènìyàn Jérúsálẹ́mù,bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìbínú mi yóò ru jáde yóò sì jó bí iná,nítorí ibi tí o ti ṣekì yóò sí ẹni tí yóò pa á.
5 “Kéde ní Júdà, kí o sì polongo ní Jérúsálẹ́mù, kí o sì wí pé:‘fun fèrè káàkiri gbogbo ilẹ̀. Kí o sì kígbe,‘kó ara jọ pọ̀!Jẹ́ kí a sálọ sí ìlú olódi.’
6 Fi àmì láti sálọ sí Síónì hàn,sálọ fún ààbò láìsí ìdádúró.Nítorí èmi ó mú àjálù láti àríwá wá,àní ìparun tí ó burú jọjọ.”
7 Kìnnìún ti sá jáde láti inú ibùgbé rẹ̀,apanirun orílẹ̀ èdè sì ti jáde.Ó ti fi àyè rẹ̀ sílẹ̀láti ba ilẹ̀ rẹ̀ jẹ́.Ìlú rẹ yóò di ahoroláìsí olùgbé.
8 Nítorí náà, gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀káàánú, kí o sì pohùnréré ẹkún,nítorí ìbínú ńlá Olúwakò tí ì kúrò lórí wa.
9 “Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí pé,“àwọn Ọba àti ìjòyè yóò pàdánù ẹ̀mí wọn,àwọn àlùfáà yóò wárìrì,àwọn wòlíì yóò sì fòyà.”
10 Nígbà náà ni mo sì wí pé, “Áà! Olúwa àwọn ọmọ-ogun, báwo ni ìwọ ti ṣe tan àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti Jérúsálẹ́mù jẹ nípa sísọ wí pé, ‘Ìwọ yóò wà ní àlàáfíà,’ nígbà tí o fẹ́ wí pé idà wà ní ọ̀fun wa.”
11 Nígbà náà ni a ó sọ fún Jérúsálẹ́mù àti àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀fúùfù líle láti aṣálẹ̀ fẹ́ lu àwọn ènìyàn mi, kì í ṣe láti sọ di mímọ́.
12 Ẹ̀fúùfù líle tí ó wá láti ọ̀dọ̀ mi. Báyìí mo kéde ìdájọ́ mi lórí wọn.”
13 Wò ó! O ń bò bí ìkuukùukẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sì wá bí ìjì líleẸ̀ṣin rẹ̀ sì yára ju idì lọÈgbé ni fún wa àwa parun.
14 Ìwọ Jérúsálẹ́mù, mú búburú kúrò lọ́kàn rẹ kí o sì yèYóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò mú èrò búburú wà ní ọkàn rẹ?
15 Ohùn kan sì ń kéde ní DánìÓ ń kókìkí ìparun láti orí òkè Éfúráímù wá.
16 “Sọ èyí fún àwọn orílẹ̀ èdè,kéde rẹ̀ fún Jérúsálẹ́mù pé:‘Ọmọ ogun ọ̀tá ń bọ̀ láti ilẹ̀ jínjìn wáWọ́n sì ń kígbe ogun láti dojú kọ ìlú Júdà.
17 Wọ́n yí i ká bí ìgbà tí àwọn ọkùnrin bá ń ṣọ́ pápá,nítorí pé ó ti dìtẹ̀ sí mi,’ ”ni Olúwa wí.
18 “Ìwà rẹ àti ìṣe rẹló fa èyí bá ọÌjìyà rẹ sì nìyìí,Báwo ló ti ṣe korò tó!Báwo ló ti ṣe gún ọkàn rẹ sí!”
19 Áà! Ìrora mi, ìrora mi!Mo yí nínú ìrora.Áà!, ìrora ọkàn mi!Ọkàn mi lù kìkì nínú mi,N kò le è dákẹ́.Nítorí mo ti gbọ́ ohùn ìpè,Mo sì ti gbọ́ igbe ogun.
20 Ìparun ń gorí ìparun;Gbogbo ilẹ̀ náà sì ṣubú sínú ìparunLọ́gán a wó àwọn àgọ́ mi,tí ó jẹ́ ohun ààbò mi níṣẹ́jú kan.
21 Yóò ti pẹ́ tó, tí èmi yóò rí oguntí èmi yóò sì gbọ́ ìró fèrè?
22 “Aṣiwèrè ni àwọn ènìyàn mi;wọn kò mọ̀ mí.Wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n ọmọ;wọ́n sì jẹ́ aláìlóye.Wọ́n mọ ibi ṣíṣe;wọn kò mọ bí a ti í ṣe rere.”
23 Mo bojú wo ayé,ó sì wà ní júujùu, ó sì ṣófoàti ní ọ̀run,ìmọ́lẹ̀ wọn kò sì sí.
24 Mo wo àwọn òkè ńlá,wọ́n wárìrì;gbogbo òkè kékèké mì jẹ̀jẹ̀.
25 Mo wò yíká n kò rí ẹnìkan;gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ló ti fò lọ.
26 Mo bojú wò, ilẹ̀ eléṣo, ó sì di aṣálẹ̀gbogbo àwọn ìlú inú rẹ̀ sì ṣubú sínú ìparunníwájú Olúwa àti níwájú ríru ìbínú rẹ̀.
27 Èyí ni ohun tí Olúwa wí“Gbogbo ìlú náà yóò sì di ahoro,síbẹ̀ èmi kì yóò pa á run pátapáta.
28 Nítorí náà, ayé yóò pohùnréré ẹkúnàwọn ọ̀run lókè yóò ṣóòkùnnítorí mo ti sọ, mo sì ti pète rẹ̀mo ti pinnu, n kì yóò sì yí i padà.”
29 Nípa ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin àti àwọn tafàtafàgbogbo ìlú yóò sálọ.Ọ̀pọ̀ sálọ sínú igbó;ọ̀pọ̀ yóò sì gun orí àpáta lọ.Gbogbo ìlú náà sì di ahoro;kò sì sí ẹnìkan nínú rẹ̀.
30 Kí ni ò ń ṣe, ìwọ tí o ti di ìjẹ tán?Ìwọ ìbá wọ ara rẹ ní aṣọ òdodokí o sì fi wúrà ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́.Àwọn olólùfẹ́ rẹ kẹ́gàn rẹwọ́n sì ń lépa ẹ̀mí rẹ.
31 Mo gbọ́ ìró kan bí i igbe obìnrin tó ń rọbí,tí ó ń rọbí, ìrora bí i abiyamọọmọbìnrin Síónì tí ń pohùnréré ẹkún ara rẹ̀.Tí ó na ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì wí pé,“Kíyèsí i mo gbé,Nítorí a ti fi ẹ̀mí mi lé àwọn apani lọ́wọ́.”