14 Ísírẹ́lì há á jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ẹrú nípa ìbí? Kí ló há adé tí ó fi di ìkógun?
15 Àwọn kìnnìún ké ramúramúwọ́n sì ń bú mọ́ wọnwọ́n ti fi ilẹ̀ rẹ̀ ṣòfòÌlú rẹ̀ ti di jíjóná, ó sìti di ìkọ̀sílẹ̀.
16 Bákan náà, àwọn ọkùnrinMémífísì àti Táfánésìwọ́n ti fa adé orí rẹ yọ.
17 Ẹ̀yin kò há a ti fa èyí sóríara yín nípa kíkọ Ọlọ́run sílẹ̀nígbà tí ó tọ́ ọ lójú ọ̀nà?
18 Kí ló dé tí o ṣe wá lọ Éjíbítìláti lọ mu omi ní Síhórì?Kí ló dé tí o sì fi lọ sí Àsíríàláti lọ mu omi ni odò Yúfúrátè náà
19 Iṣẹ́ búburú yín yóò fìyà jẹ yínÌpàdàṣẹ́yìn rẹ yóò sì bá ọ wímọ̀ kí o sì ríi wí pé ibi àtiohun búburú yóò sì jẹ́ tìrẹnígbà tí o ti kọ Ọlọ́run ọmọogun sílẹ̀, ẹ kò sì ní ìbẹ̀rù fún mi,”ni Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí.
20 “Nígbà àtijọ́, o ti fọ́ àjàgàrẹ sọnù, ìwọ sì já ìdè rẹìwọ wí pé, ‘Èmi kì yóò sìn ọ́!’Lóòtọ́, lórí gbogbo òkè gíga niàti lábẹ́ igi tí ó tàn kálẹ̀ni ìwọ dùbúlẹ̀ sí gẹ́gẹ́ bí panṣágà.