4 Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ìdílé Jákọ́bùàti gbogbo ẹ̀yin ará ilé Ísírẹ́lì.
5 Báyìí ni Olúwa wí:“Irú àwọn àìṣedédé wo ni baba yín rí nínú mi?Tí wọ́n fi jìnnà sími? Wọ́n tẹ̀léàwọn òrìṣà tí kò jámọ́ nǹkan kanàwọn fúnra wọn sì jẹ́ ènìyàn yẹpẹrẹ.
6 Wọn kò béèrè, ‘Níbo ni Olúwa wà tí ó mú wọn,jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì, tí ó mú wala ihà já, tí ó mu wọn la àárin àwọnaṣálẹ̀ àti òkè láàrin ìyàngbẹ ilẹ̀àti òkùnkùn wá ilẹ̀ ibi tí ẹnikẹ́nikò ti rìnrìn-àjò, tí ẹníkẹ́ni kò sì gbé?’
7 Mo mú yín wá sí ilẹ̀ ọlọ́ràá láti máajẹ èso ibẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀, ẹ̀yin sì wá, ẹ sìba ilẹ̀ náà jẹ́, ẹ sì mú àwọnohun ogún mi di ohun ìríra.
8 Àlùfáà kò bèèrè wí pé níbo ni Olúwa wà? Àwọn tí ń ṣiṣẹ́pẹ̀lú òfin kò si mọ̀ mí, àwọnolórí wọn sì gbógun sí mi,àwọn wòlíì sì ń sọ tẹ́lẹ̀ nípaòrìṣà báálì, wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọnòrìṣà yẹpẹrẹ.
9 “Nítorí náà, mo fi ẹ̀sùn kàn yín lẹ́ẹ́kan síi,”ni Olúwa wí.“Èmi ó sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ọwọ́ rẹ
10 Rékọjá sí ẹkùn kan kítímì, kí osì wò ó, ránṣẹ́ sí kéda, kí o sìwò ó dáradára, wò ó kí ẹ sìwò ó bí irú nǹkan báyìí báwà níbẹ̀ rí?