1 Báyìí ni Olúwa wí, “Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ààfin Ọba Júdà, kí o sì sọ ọ̀rọ̀ yìí níbẹ̀:
2 ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ìwọ Ọba Júdà, tí ó jókòó ní Ìtẹ́ Dáfídì, ìwọ, àwọn ènìyàn rẹ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí ó wọlé láti ẹnu ibodè wọ̀nyí.
3 Báyìí ni Olúwa wí: Ṣé ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ tí ó sì yẹ, kí o sì gba ẹni tí a fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú kúrò lọ́wọ́ aninilára. Má ṣe hu ìwà ìpanilára, tàbí opó, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ níbí yìí.
4 Nítorí bí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, nígbà náà ni àwọn Ọba inú ààfin láti ẹnu ọ̀nà, wọn yóò gun kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin, àwọn àti ìránṣẹ́ wọn àti àwọn ènìyàn wọn.
5 “Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, mo búra fúnra mi pé ààfin yìí yóò di ìparun ni Olúwa wí.’ ”
6 Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa ààfin Ọba Júdà,“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ dàbí Gílíádì sí mi,gẹ́gẹ́ bí góńgó òkè Lẹ́bánónì,dájúdájú Èmi yóò sọ ọ́ di aṣálẹ̀,àní gẹ́gẹ́ bí ìlú tí a kò gbé inú wọn.