11 Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa Ṣálúmù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà tí ó jọba lẹ́yìn baba rẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó jáde kúrò níhìn ín: “Òun kì yóò padà wá mọ́.
12 Yóò kú ni ibi tí a mú u ní ìgbèkùn lọ, kì yóò sì rí ilẹ̀ yìí mọ́.”
13 “Ègbé ni fún ẹni tí a kọ́ ààfin rẹ̀ lọ́nà àìsòdodo,àti àwọn yàrá òkè rẹ̀ lọ́nà àìtọ́tí ó mú kí àwọn ará ìlú rẹ ṣiṣẹ́ lásánláì san owó iṣẹ́ wọn fún wọn.
14 Ó wí pé, ‘Èmi ó kọ́ ààfin ńlá fún ara miàwọn yàrá òkè tí ó fẹ̀,ojú fèrèsé rẹ̀ yóò tóbi.’A ó sì fi igi kédárì bò ó,a ó fi ohun aláwọ̀ pupa ṣe é ní ọ̀ṣọ́.
15 “Nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kédárì, a sọ ọ́ di Ọbababa rẹ kò ha ní ohun jíjẹ àti mímu?Ó ṣe ohun tí ó tọ́ ni ó fi dára fún un.
16 Ó gbéjà òtòsì àti aláìní,ohun gbogbo sì dára fún un.Ìyẹn ha kọ́ ni mímọ́ mi túmọ̀ sí?”ni Olúwa wí.
17 “Ṣùgbọ́n ojú àti ọkàn rẹwà lára rẹ̀ ní èrè àìsòtítọ́láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ìnilára àti ìlọ́nilọ́wọ́gbà.”