17 “Ṣùgbọ́n ojú àti ọkàn rẹwà lára rẹ̀ ní èrè àìsòtítọ́láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ìnilára àti ìlọ́nilọ́wọ́gbà.”
18 Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí, nípa Jehóíákímù ọmọ Jòsáyà, Ọba Júdà:“Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un:wí pé, ‘Ó ṣe, arákùnrin mi! Ó ṣe, arábìnrin mi!’Wọn kì yóò sọ̀fọ̀ fún un:wí pé, ‘Ó ṣe, olúwa tàbí ó ṣe kábíyèsí!’
19 A ó sin òkú rẹ̀ bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́tí a wọ́ sọnù gba ti ẹnubodèJérúsálẹ́mù.”
20 “Gòkè lọ sí Lẹ́bánónì, kígbe sítakí a sì gbọ́ ohùn rẹ ní Básánì,kí o kígbe sókè láti Ábárímù,nítorí a ti run gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ túútúú.
21 Èmi ti kìlọ̀ fún ọ nígbà tí o rò pé kò séwu,ṣùgbọ́n o sọ pé, ‘Èmi kì yóò fetísílẹ̀!’Èyí ni iṣẹ́ rẹ láti ìgbà èwe rẹ,ìwọ kò fìgbà kan gba ohùn mi gbọ́.
22 Ẹ̀fúùfù yóò lé gbogbo àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ̀ lọ,gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ yóò lọ sí ìgbékùn,nígbà náà ni a ó kẹ́gàn rẹ, ojú yóò tì ọ́nítorí gbogbo ìwà búburú rẹ.
23 Ìwọ tí ń gbé ‘Lẹ́bánónì,’tí ó tẹ́ ìtẹ́ sí orí igi kédárì,ìwọ yóò ti kérora pẹ́ tó, nígbà tí ìrora bá dé bá ọ,ìrora bí i ti obìnrin tí ń rọbí!