Jeremáyà 22:5-11 BMY

5 “Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, mo búra fúnra mi pé ààfin yìí yóò di ìparun ni Olúwa wí.’ ”

6 Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa ààfin Ọba Júdà,“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ dàbí Gílíádì sí mi,gẹ́gẹ́ bí góńgó òkè Lẹ́bánónì,dájúdájú Èmi yóò sọ ọ́ di aṣálẹ̀,àní gẹ́gẹ́ bí ìlú tí a kò gbé inú wọn.

7 Èmi ó rán apanirun sí ọolúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀,wọn yóò sì gé àsànyàn igi kédárì rẹ lulẹ̀,wọn ó sì kó wọn jù sínú iná.

8 “Àwọn ènìyàn láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè yóò rékọjá lẹ́bàá ìlú yìí wọn yóò sì máa bi ara wọn léèrè pé, ‘Èéṣe tí Olúwa ṣe irú èyí sí ìlú ńlá yìí?’

9 Ìdáhùn wọn yóò sì jẹ́: ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, wọn ti ń fi oríbalẹ̀ fún Ọlọ́run mìíràn, wọ́n sì sìn wọ́n.’ ”

10 Nítorí náà má ṣe sunkún nítorí Ọba tí ó ti kú tàbí sọ̀fọ̀ fún àdánù rẹ̀,ṣùgbọ́n ẹ sunkún kíkorò fún ẹni tí a lé kúrò nílùúnítorí kì yóò padà wá mọ́tàbí fi ojú rí ilẹ̀ tí a ti bí i.

11 Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa Ṣálúmù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà tí ó jọba lẹ́yìn baba rẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó jáde kúrò níhìn ín: “Òun kì yóò padà wá mọ́.