9 Ìdáhùn wọn yóò sì jẹ́: ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, wọn ti ń fi oríbalẹ̀ fún Ọlọ́run mìíràn, wọ́n sì sìn wọ́n.’ ”
10 Nítorí náà má ṣe sunkún nítorí Ọba tí ó ti kú tàbí sọ̀fọ̀ fún àdánù rẹ̀,ṣùgbọ́n ẹ sunkún kíkorò fún ẹni tí a lé kúrò nílùúnítorí kì yóò padà wá mọ́tàbí fi ojú rí ilẹ̀ tí a ti bí i.
11 Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa Ṣálúmù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà tí ó jọba lẹ́yìn baba rẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó jáde kúrò níhìn ín: “Òun kì yóò padà wá mọ́.
12 Yóò kú ni ibi tí a mú u ní ìgbèkùn lọ, kì yóò sì rí ilẹ̀ yìí mọ́.”
13 “Ègbé ni fún ẹni tí a kọ́ ààfin rẹ̀ lọ́nà àìsòdodo,àti àwọn yàrá òkè rẹ̀ lọ́nà àìtọ́tí ó mú kí àwọn ará ìlú rẹ ṣiṣẹ́ lásánláì san owó iṣẹ́ wọn fún wọn.
14 Ó wí pé, ‘Èmi ó kọ́ ààfin ńlá fún ara miàwọn yàrá òkè tí ó fẹ̀,ojú fèrèsé rẹ̀ yóò tóbi.’A ó sì fi igi kédárì bò ó,a ó fi ohun aláwọ̀ pupa ṣe é ní ọ̀ṣọ́.
15 “Nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kédárì, a sọ ọ́ di Ọbababa rẹ kò ha ní ohun jíjẹ àti mímu?Ó ṣe ohun tí ó tọ́ ni ó fi dára fún un.