Jeremáyà 23:3-9 BMY

3 “Èmi Olúwa tìkálárami yóò kó ìyókù agbo ẹran mi jọ láti inú gbogbo orílẹ̀ èdè tí mo ti lé wọn, Èmi yóò mú wọn padà sínú pápá oko wọn, níbẹ̀ ni wọn ó ti bí síi, tí wọn ó sì pọ̀ síi.

4 Èmi ó wá olùṣọ́ àgùntàn fún wọn, tí yóò darí wọn, wọn kì yóò bẹ̀rù tàbí dààmú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan kì yóò sọnù,” ni Olúwa wí.

5 “Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí,“tí Èmi yóò gbé ẹ̀ka òdodo dìde fún Dáfídì,Ọba tí yóò lo ìjọba pẹ̀lú ọgbọ́ntí yóò sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ lórí ilẹ̀ náà.

6 Ní ọjọ́ rẹ̀ ni a ó gba Júdà là,Ísírẹ́lì yóò sì máa gbé ní aláìléwuÈyí ni orúkọ tí a ó fi máa pè é: Olúwa Òdodo wa.

7 “Nítorí náà, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí ènìyàn kì yóò tún wí pé, ‘Dájúdájú Olúwa wà láàyè tí ó mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì.’

8 Ṣùgbọ́n wọn yóò máa wí pé, ‘Dájúdájú Olúwa ń bẹ tí ó mú irú ọmọ ilé Ísírẹ́lì wá láti ilẹ̀ àríwá àti láti àwọn ilẹ̀ ibi tí mo tí lé wọn lọ,’ wọn ó sì gbé inú ilẹ̀ wọn.”

9 Nípa ti àwọn wòlíì èké:Ọkàn mi ti bàjẹ́ nínú mi,gbogbo egungun mi ni ó wárìrì.Èmi dàbí ọ̀mùtí ènìyàn,bí ọkùnrin tí ọtí wáìnì ń pa;nítorí Olúwa àti àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀.