Jeremáyà 24:2-8 BMY

2 Agbọ̀n kan ni èṣo ọ̀pọ̀tọ́ tí ó dára bí èyí tí ó tètè pọ́n; èkejì sì ní èṣo ọ̀pọ̀tọ́ tí ó burú rékọjá tí kò sì le è ṣe é jẹ

3 Nígbà náà ni Olúwa bi mí pé, “Kí ni ìwọ rí Jeremáyà?”“Èṣo ọ̀pọ̀tọ́” Mo dáhùn. “Èyí tí ó dára dára púpọ̀, ṣùgbọ́n èyí tí ó burú burú rékọjá tí kò sì ṣe é jẹ.”

4 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

5 “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Gẹ́gẹ́ bí àwọn èṣo ọ̀pọ̀tọ́ dáradára yìí ni Èmi yóò ka àwọn tí wọ́n lọ sí ilẹ̀ àjòjì láti Júdà sí tí èmi rán jáde kúrò ní ibí yìí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará kálídéà

6 Ojú mi yóò máa ṣọ́ wọn lọ fún rere; Èmi yóò gbé wọn ró, n kò ní já wọn lulẹ̀. Èmi yóò gbìn wọ́n, n kò sì ní fà wọ́n tu.

7 Èmi yóò fún wọn ní ọkàn láti mọ̀ mí pé, Èmi ni Olúwa. Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi; Èmi ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn; nítorí pé wọn yóò padà sọ́dọ̀ mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.

8 “ ‘Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí èṣo ọ̀pọ̀tọ́ tí kò dára, tí ó burú tí kò ṣe é jẹ,’ ni Olúwa wí, ‘bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò ṣe pẹ̀lú Ṣedekáyà Ọba Júdà, àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn tí ó yẹ ní Jérúsálẹ́mù, yálà wọ́n wà lórí ilẹ̀ yìí tàbí wọ́n ń gbé Éjíbítì.