Jeremáyà 26:12-18 BMY

12 Nígbà náà ni Jeremáyà sọ fún gbogbo àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn wí pé: “Olúwa rán mi láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé yìí àti ìlú yìí, gbogbo ohun tí ẹ ti gbọ́.

13 Nísinsìnyìí, tún ọ̀nà rẹ ṣe àti ìṣe rẹ, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run yín. Olúwa yóò yí ọkàn rẹ̀ padà, kò sì ní mú ohun gbogbo tí ó ti sọ jáde ní búburú ṣẹ lórí yín.

14 Bí ó bá ṣe tèmi ni, èmi wà ní ọwọ́ yín, ẹ ṣe ohun tí ẹ̀yin bá rò pé ó dára, tí ó sì tọ́ lójú yín fún mi.

15 Ẹ mọ̀ dájú pé tí ẹ bá pa mí, ẹ ó mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ wá sórí ara yín, sórí orílẹ̀ èdè yìí àti àwọn olùgbé inú rẹ̀; nítorí pé nítòótọ́ ni Olúwa ti rán mi láti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un yín.”

16 Nígbà náà ni àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì pé, “Ẹ má ṣe pa ọkùnrin yìí nítorí ó ti bá wa sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ ogun.”

17 Lára àwọn àgbààgbà ilẹ̀ náà sì sún ṣíwájú, wọ́n sì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà wí pé,

18 “Míkà ti Mórásì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ọjọ́ Heṣekáyà Ọba Júdà. Ó sọ fún gbogbo ènìyàn Júdà pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“ ‘A ó sì fa Síónì tu bí okoJérúsálẹ́mù yóò di òkítìàlàpà àti òkè ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bíibi gíga igbó.’