1 Ní oṣù karùn ún ní ọdún kan náà, ọdún kẹrin ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba Sedekáyà Ọba Júdà, wòlíì Hananáyà ọmọ Ásúrì, tí ó wá láti Gíbíónì, sọ fún mi ní ilé Olúwa tí ó wà ní iwájú àwọn àlùfáà àti gbogbo ènìyàn:
2 “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Èmi yóò mú àjàgà Ọba Bábílónì rọrùn.
3 Láàrin ọdún méjì, mà á mú gbogbo ohun èlò tí Ọba Nebukadinésárì; Ọba Bábílónì kó kúrò ní ilé Olúwa tí ó sì kó lọ sí Bábílónì padà wá.
4 Èmi á tún mú àyè Jéhóíákínì ọmọ Jéhóíákímù Ọba Júdà padà, àti gbogbo àwọn tí ń ṣe àtìpó láti Júdà ní Bábílónì,’ èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa pé, ‘àjàgà yín láti ọwọ́ Ọba Bábílónì yóò rọrùn.’ ”
5 Wòlíì Jeremáyà fún wòlíì Hananáyà lésì ní iwájú ọmọ àlùfáà àti àwọn ènìyàn tí wọ́n dúró ní ilé Olúwa.