1 “Nígbà náà, Èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo ìdílé ìran Ísírẹ́lì, àwọn náà yóò sì jẹ́ ènìyàn mi,” ni Olúwa wí.
2 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Àwọn ènìyàn tí ó sá àsálà lọ́wọ́ idàyóò rí ojúrere Olúwa ní aṣálẹ̀,Èmi yóò sì fi ìsinmi fún Ísírẹ́lì.”
3 Olúwa ti fi ara rẹ̀ hàn wá ní ìgbà kan rí, ó wí pé:“Èmi ti nífẹ̀ẹ́ yín pẹ̀lú ìfẹ́ àìlópin;mo ti fi ìfẹ́ ńlá fà yín,
4 Èmi yóò tún gbé e yín sókè,àní a ó tún gbé e yín ró iwọ wúndíá ilẹ̀ Ísírẹ́lì.Àní ẹ ó tún tún ohun èlò orin yín gbé,ẹ ó sì jáde síta pẹ̀lú ijó àti ayọ̀.