2 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Àwọn ènìyàn tí ó sá àsálà lọ́wọ́ idàyóò rí ojúrere Olúwa ní aṣálẹ̀,Èmi yóò sì fi ìsinmi fún Ísírẹ́lì.”
3 Olúwa ti fi ara rẹ̀ hàn wá ní ìgbà kan rí, ó wí pé:“Èmi ti nífẹ̀ẹ́ yín pẹ̀lú ìfẹ́ àìlópin;mo ti fi ìfẹ́ ńlá fà yín,
4 Èmi yóò tún gbé e yín sókè,àní a ó tún gbé e yín ró iwọ wúndíá ilẹ̀ Ísírẹ́lì.Àní ẹ ó tún tún ohun èlò orin yín gbé,ẹ ó sì jáde síta pẹ̀lú ijó àti ayọ̀.
5 Ẹ ó tún dá okoní orí òkè Saáríà;àwọn àgbẹ̀ yóò sì máagbádùn èso oko wọn.
6 Ọjọ́ kan máa wà tí àwọn olùṣọ́ yóò kígbe jádelórí òkè Éfráímù wí pé,‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ sí Síónì,ní ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa.’ ”
7 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ wí pé:“Ẹ fi ayọ̀ Kọrin sí Jákọ́bù;ẹ hó sí olórí àwọn orílẹ̀ èdè gbogbo.Jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ìyìn rẹ kí o sì wí pé,‘Olúwa, gba àwọn ènìyàn rẹ là;àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Ísírẹ́lì.’
8 Wò ó, Èmi yóò mú wọn wá láti ilẹ̀ àríwá;èmi yóò kó gbogbo wọn jọ láti òpin ayé.Lára wọn ni yóò jẹ́ afọ́jú àti arọ,aboyún àti obìnrin tí ń rọbí,ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wá.