Jeremáyà 31:7-13 BMY

7 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ wí pé:“Ẹ fi ayọ̀ Kọrin sí Jákọ́bù;ẹ hó sí olórí àwọn orílẹ̀ èdè gbogbo.Jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ìyìn rẹ kí o sì wí pé,‘Olúwa, gba àwọn ènìyàn rẹ là;àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Ísírẹ́lì.’

8 Wò ó, Èmi yóò mú wọn wá láti ilẹ̀ àríwá;èmi yóò kó gbogbo wọn jọ láti òpin ayé.Lára wọn ni yóò jẹ́ afọ́jú àti arọ,aboyún àti obìnrin tí ń rọbí,ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wá.

9 Wọn yóò wá pẹ̀lú ẹkún,wọn yóò gbàdúrà bí Èmi yóò ṣe mú wọn padà.Èmi yóò jẹ́ atọ́nà fún wọn ní ẹ̀bá odò omi;ní ọ̀nà tí ó tẹ́jú tí wọn kì yóò le ṣubú,nítorí èmi ni baba Ísírẹ́lì,Éfúráímù sì ni àkọ́bí ọkùnrin mi.

10 “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin orílẹ̀ èdèẹ kéde rẹ̀ ní erékùsù jínjìn;‘Ẹni tí ó bá tú Ísírẹ́lì ká yóò kójọ,yóò sì ṣọ́ agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn.’

11 Nítorí Olúwa ti tú Jákọ́bù sílẹ̀, o sì ràá padàní ọwọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ

12 Wọn yóò wá, wọn ó sì hó ìhó ayọ̀ lórí òkè Síónì;wọn yóò yọ ayọ̀ níbi oore Olúwa.Àlìkámà ni, ọtí wáìnì tuntun àti òróróọ̀dọ́ àgùntàn àti ọ̀dọ́ ọ̀wọ́ ẹran.Wọn ó dàbí ọgbà àjàrà tí a bomirin,ìkorò kò ní bá wọn mọ́.

13 Àwọn wúndíá yóò jó, wọn ó sì kún fún ayọ̀,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọkùnrin àti obìnrin.Èmi yóò sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀,dípò ìkorò èmi yóò tù wọ́n nínú.Èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀.