12 Èmi sì fi èyí fún Bárúkì ọmọkùnrin ọmọ ẹ̀gbọ́n mi àti níwájú àwọn ẹlẹ́rìí tí ó ti fi ọwọ́ sí ìwé àti ní ojú àwọn Júù gbogbo tí wọ́n jókòó ní àgbàlá túbú.
13 “Ní ojú wọn ni èmi ti pàṣẹ fún Bárúkì pé:
14 Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí; mú àwọn ìwé tí a fi rà á wọ̀nyí, àti èyí tí a lẹ̀ àti èyí tí a kò lẹ̀, kí o wá gbé wọn sínú ìkòkò amọ̀, kí wọn ó lè wà ní ọjọ́ púpọ̀.
15 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí; àwọn ilẹ̀, pápá àti ọgbà àjàrà ni à ó tún rà padà nílẹ̀ yìí.
16 “Lẹ́yìn tí mo ti fi ìwé rírà náà fún Bárúkì ọmọkùnrin Néráyà, mo gbàdúrà sí Olúwa wí pé:
17 “Áà! Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbogbo, ìwọ tí o dá ọ̀run àti ayé pẹ̀lú títóbi agbára rẹ àti gbogbo ọ̀rọ̀ apá rẹ. Kò sí ohun tí ó ṣòro fún ọ láti ṣe.
18 O fi ìfẹ́ hàn sí ẹgbẹ̀gbẹ̀rún àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n o gbé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba lé àwọn ọmọ lẹ́yìn wọn. Ọlọ́rùn títóbi àti alágbára, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ.