11 Nígbà náà ni a ó sọ fún Jérúsálẹ́mù àti àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀fúùfù líle láti aṣálẹ̀ fẹ́ lu àwọn ènìyàn mi, kì í ṣe láti sọ di mímọ́.
12 Ẹ̀fúùfù líle tí ó wá láti ọ̀dọ̀ mi. Báyìí mo kéde ìdájọ́ mi lórí wọn.”
13 Wò ó! O ń bò bí ìkuukùukẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sì wá bí ìjì líleẸ̀ṣin rẹ̀ sì yára ju idì lọÈgbé ni fún wa àwa parun.
14 Ìwọ Jérúsálẹ́mù, mú búburú kúrò lọ́kàn rẹ kí o sì yèYóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò mú èrò búburú wà ní ọkàn rẹ?
15 Ohùn kan sì ń kéde ní DánìÓ ń kókìkí ìparun láti orí òkè Éfúráímù wá.
16 “Sọ èyí fún àwọn orílẹ̀ èdè,kéde rẹ̀ fún Jérúsálẹ́mù pé:‘Ọmọ ogun ọ̀tá ń bọ̀ láti ilẹ̀ jínjìn wáWọ́n sì ń kígbe ogun láti dojú kọ ìlú Júdà.
17 Wọ́n yí i ká bí ìgbà tí àwọn ọkùnrin bá ń ṣọ́ pápá,nítorí pé ó ti dìtẹ̀ sí mi,’ ”ni Olúwa wí.