3 Ṣùgbọ́n Bárúkù ọmọ Néríà ń kó sí ọ lọ́kàn sí wa láti fàwá lé Bábílónì lọ́wọ́, kí wọn le pa wá tàbí kó wa sí ìgbékùn Bábílónì.”
4 Nítorí náà, Jóhánánì ti Káréà àti àwọn ọ̀gágun, àti gbogbo àwọn ènìyàn tàpá sí àṣẹ Olúwa nípa dídúró sí Júdà.
5 Dípò bẹ́ẹ̀, Jóhánánì ọmọ Káréà àti àwọn ọ̀gágun sì ko àwọn àjẹkù Júdà tí wọ́n wá láti gbé ilẹ̀ Júdà láti orílẹ̀-èdè gbogbo tí wọ́n ti tú wọn ká.
6 Wọ́n tún kó àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, àti àwọn ọmọ Ọba tí ó jẹ́ obìnrin èyí tí Nebusàrádánì tí ó jẹ́ adarí ogun ọ̀wọ́ tí ó jẹ́ olùsọ́ ti fi sílẹ̀ pẹ̀lú Jedaháyà ọmọ Élíkámù, ọmọ Sáfánì, àti Jeremáyà wòlíì náà àti Bárúkù ọmọ Néríà.
7 Nítorí náà, wọn wọ Éjíbítì pẹ̀lú àìgbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa, wọ́n sì lọ títí dé Táfánésì.
8 Ní Táfánésì ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá:
9 “Nígbà tí àwọn Júù ń wòye mú àwọn òkúta pẹ̀lú rẹ, kí o sì rì wọ́n mọ́ inú amọ̀ tí ó wà nínú bíríkì tí ó wà níbi pèpéle ẹnu ọ̀nà ààfin Fáráò ní Táfánésì.