7 “Kí ni ṣe tí èmi ó ṣe dáríjì ọ́?Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀àti pé wọ́n ti fi ọlọ́run tí kì í ṣe Ọlọ́run búra.Mo pèṣè fún gbogbo àìní wọn,síbẹ̀ wọ́n tún ń ṣe panṣágàwọ́n sì kórajọ sí ilé àwọn alágbérè.
8 Wọ́n jẹ́ akọ ẹṣin tí a bọ́ yó,tí ó lágbára, wọ́n sì ń sunkún sí aya arákùnrin wọn.
9 Èmi kì yóò ṣàì fìyà jẹ wọ́n fún èyí?”ni Olúwa wí.“Èmi kì yóò wá gba ẹ̀san fúnra milára irú orílẹ̀ èdè bí èyí bí?
10 “Lọ sí ọgbà àjàrà rẹ̀, kí ẹ sì pa wọ́n run,ẹ má ṣe pa wọ́n run pátapáta.Ya ẹ̀ka rẹ̀ kúrò,nítorí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ti Olúwa.
11 Ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdàti jẹ́ aláìsòdodo sí mi,”ni Olúwa wí.
12 Wọ́n ti pa irọ́ mọ́ Olúwa;wọ́n wí pé, “Òun kì yóò ṣe ohun kan!Ibi kan kì yóò sì tọ̀ wá wá;àwa kì yóò sì rí idà tàbí ìyàn.
13 Àwọn wòlíì wá dàbí afẹ́fẹ́,ọ̀rọ̀ kò sí nínú wọn.Nítorí náà, jẹ́ kí ohun tí wọ́n bá sọ ṣẹlẹ̀ sí wọn.”