1 Ohùn ti Olúwa nìyìí:“wò ó èmi yóò ru ẹ̀míapanirun kan sókè síBábílónì àwọn ènìyàn Lébíkámáì
2 Èmi yóò rán àwọn àjèjì ènìyàn síBábílónì láti ba ilẹ̀ jẹ́,wọn yóò ṣe àtakò rẹ̀ ní gbogboọ̀nà ní ọjọ́ ìparun rẹ̀.
3 Má ṣe jẹ́ kí tafàtafà yọ ọfà rẹ̀jáde tàbí kí o di ìhámọ́ra rẹ̀;má ṣe dá àwọn ọdọ́mọkùnrinsí, pátapáta ni kí o pa àwọn ọmọ ogun rẹ̀.
4 Gbogbo wọn ni yóò ṣubúní Bábílónì tí wọn yóò sìfarapa yánna yànna ní òpópónà.
5 Nítorí pé Júdà àti Ísírẹ́lì niỌlọ́run wọn tí í se Olúwa alágbárakò gbàgbọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ilé wọnkún fún kìki ẹ̀bi níwájú ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì.
6 “Sá kúrò ní Bábílónì! Sá àsálàfún ẹ̀mí rẹ! Má ṣe ṣègbé torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.Àsìkò àti gbẹ̀san Ọlọ́run ni èyí,yóò sán fún òun gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́.