1 Ọ̀rọ̀ tí Jeremaya gbọ́ lẹ́nu OLUWA nìyí nígbà tí ọba Sedekaya rán Paṣuri, ọmọ Malikaya, ati alufaa Sefanaya, ọmọ Maaseaya, sí i;
2 tí ọba Sedekaya ní, “Ẹ sọ fún Jeremaya pé kí ó bá wa ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ OLUWA nípa Nebukadinesari, ọba Babiloni, tí ó gbógun tì wá; bóyá OLUWA yóo ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún wa, kí Nebukadinesari kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ wa.”
3 Jeremaya sọ fun awọn tí wọn rán sí i,
4 kí wọ́n sọ fún Sedekaya pé OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, “N óo gba àwọn ohun ìjà tí ó wà lọ́wọ́ yín, tí ẹ fi ń bá ọba Babiloni ati àwọn ará Kalidea tí wọn gbógun tì yín lẹ́yìn odi jà, n óo dá wọn pada sí ààrin ìlú, n óo sì dojú wọn kọ yín.
5 Èmi fúnra mi ni n óo ba yín jà. Ipá ati agbára, pẹlu ibinu ńlá, ati ìrúnú gbígbóná ni n óo fi ba yín jà.
6 N óo fi àjàkálẹ̀ àrùn ńlá kọlu àwọn ará ìlú yìí, ati eniyan ati ẹranko ni yóo sì kú.
7 Lẹ́yìn náà n óo mú Sedekaya ọba Juda, ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ati àwọn tí àjàkálẹ̀ àrùn, ogun, ati ìyàn, bá pa kù ní ìlú yìí, n óo fi wọ́n lé Nebukadinesari, ọba Babiloni lọ́wọ́, òun ati àwọn ọ̀tá tí ń wá ọ̀nà láti pa wọ́n. Ọba Babiloni yóo fi idà pa wọ́n, kò ní ṣàánú wọn, kò sì ní dá ẹnikẹ́ni sí.”