Jeremaya 27:16-22 BM

16 Lẹ́yìn náà, mo bá àwọn alufaa ati gbogbo àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀, mo ní, “OLUWA sọ pé ẹ kò gbọdọ̀ fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii yín tí wọn ń wí fun yín pé wọn kò ní pẹ́ kó àwọn ohun èlò ilé èmi OLUWA pada wá láti Babiloni. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín.

17 Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ wọn. Ẹ sin ọba Babiloni, kí ẹ lè wà láàyè. Kí ló dé tí ìlú yìí yóo fi di ahoro?

18 Bí wọn bá jẹ́ wolii nítòótọ́, bí ó bá jẹ́ pé èmi OLUWA ni mo fi ọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́nu, ẹ ní kí wọn gbadura sí èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, kí n má jẹ́ kí wọ́n kó àwọn ohun èlò tí ó kù ní ilé OLUWA ati ní ààfin ọba Juda ati ní Jerusalẹmu lọ sí Babiloni.”

19 Àwọn ohun èlò kan ṣẹ́kù ninu ilé OLUWA, àwọn bíi: òpó ilé, ati agbada omi tí a fi idẹ ṣe, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ati àwọn ohun èlò tí ó kù ninu ìlú yìí,

20 tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, kò kó lọ, nígbà tí ó kó Jehoiakini, ọba Juda, ọmọ Jehoiakimu, ati gbogbo àwọn ọlọ́lá Juda ati ti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni.

21 OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Gbogbo àwọn ohun èlò tí ó ṣẹ́kù ní ilé rẹ, ati ní ààfin ọba Juda, ati ní Jerusalẹmu, ni

22 wọn óo kó lọ sí Babiloni, níbẹ̀ ni wọn yóo sì wà títí di ọjọ́ tí mo bá ranti wọn. N óo wá kó wọn pada wá sí ibí yìí nígbà náà.”