21 A gbọ́ ohùn kan lórí àwọn òkè gíga,ẹkún ati ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọkunrin Israẹli ni.Nítorí wọ́n ti yapa kúrò lójú ọ̀nà wọn;wọ́n ti gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn.
22 Ẹ yipada, ẹ̀yin alaiṣootọ ọmọ,n óo mú aiṣootọ yín kúrò.“Wò wá! A wá sọ́dọ̀ rẹ,nítorí ìwọ ni OLUWA Ọlọrun wa.
23 Nítòótọ́, ẹ̀tàn ni àwọn òkè,ati gbogbo ohun tí wọn ń lọ ṣe níbẹ̀;dájúdájú lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun wa ni ìgbàlà Israẹli wà.
24 Ṣugbọn láti ìgbà èwe wa ni ohun ìtìjú yìíti pa gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá wa ṣiṣẹ́ fún run:ẹran ọ̀sìn wọn, ati agbo mààlúù wọn,àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin.
25 Ẹ jẹ́ kí á dojúbolẹ̀ kí ìtìjú wa sì bò wá,nítorí pé a ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun wa;àtàwa, àtàwọn baba ńlá wa,a kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun wa, láti ìgbà èwe wa títí di òní.”