12 Ilé wọn yóo di ilé onílé,oko wọn, ati àwọn aya wọn pẹlu, yóo di ti ẹni ẹlẹ́ni.Nítorí pé n óo na ọwọ́ ibinu mi sí àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
13 OLUWA ní, “Láti orí àwọn mẹ̀kúnnù títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki,gbogbo wọn ni wọ́n fẹ́ràn èrè àjẹjù;láti orí àwọn wolii títí dé orí àwọn alufaa,èké ni gbogbo wọn.
14 Wọn kò wẹ egbò àwọn eniyan mi jiná,wọ́n ń kígbe pé: ‘Alaafia ni, alaafia ni’,nígbà tí kò sí alaafia.
15 Ǹjẹ́ ojú a tilẹ̀ máa tì wọ́n nígbà tí wọ́n bá ń hu ìwà ìbàjẹ́?Rárá o, ojú kì í tì wọ́n; nítorí pé wọn kò lójútì.Nítorí náà, àwọn náà óo ṣubú nígbà tí àwọn yòókù bá ṣubú,a ó bì wọ́n ṣubú nígbà tí mo bá ń jẹ wọ́n níyà,Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
16 OLUWA ní,“Ẹ lọ dúró ní oríta kí ẹ wo òréré,ẹ bèèrè àwọn ọ̀nà àtijọ́,níbi tí ọ̀nà dáradára wà, kí ẹ sì máa tọ̀ ọ́.Kí ẹ lè ní ìsinmi.”Ṣugbọn wọ́n kọ̀, wọ́n ní,“A kò ní tọ ọ̀nà náà.”
17 Mo fi àwọn aṣọ́nà ṣọ́nà nítorí yín.Mo wí fún wọn pé,“Ẹ máa dẹtí sílẹ̀ sí fèrè ogun!”Ṣugbọn wọ́n ní, “A kò ní dẹtí sílẹ̀.”
18 OLUWA ní, “Nítorí náà, ẹ gbọ́, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,kí ẹ̀yin eniyan sì mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn.