26 Ẹ̀yin eniyan mi,ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ máa yí ninu eérú;ẹ máa ṣọ̀fọ̀, bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo;kí ẹ sì máa sunkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóo bò yín.
27 Mo ti fi ọ́ ṣe ẹni tí yóo máa dán àwọn eniyan mi wò,o óo máa dán wọn wò bí ẹni dán irin wò,o óo gbìyànjú láti mọ ọ̀nà wọn,kí o lè yẹ ọ̀nà wọn wò, kí o sì mọ̀ ọ́n.
28 Ọlọ̀tẹ̀, aláìgbọràn ni gbogbo wọn,wọn á máa sọ̀rọ̀ eniyan lẹ́yìn.Wọ́n dàbí idẹ àdàlú mọ́ irin,àmúlùmálà ni gbogbo wọn.
29 Lóòótọ́ à ń fi ẹwìrì fẹ́ iná,òjé sì ń yọ́ lórí iná;ṣugbọn alágbẹ̀dẹ ń yọ́ irin lásán ni,kò mú ìbàjẹ́ ara rẹ̀ kúrò.
30 Ìdọ̀tí fadaka tí a kọ̀ tì ni wọ́n,nítorí pé OLUWA ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀.