Jeremaya 9:10-16 BM

10 Mo ní, “Gbé ẹnu sókè kí o sọkún nítorí àwọn òkè ńlá,sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn nítorí àwọn pápá inú aṣálẹ̀,nítorí gbogbo wọn ti di ahoro, láìsí ẹnìkan tí yóo la ààrin wọn kọjá.A kò ní gbọ́ ohùn ẹran ọ̀sìn níbẹ̀.Ati ẹyẹ, ati ẹranko, gbogbo wọn ti sá lọ.”

11 OLUWA ní, “N óo sọ Jerusalẹmu di àlàpà ati ibùgbé ajáko.N óo sọ àwọn ìlú Juda di ahoroẹnikẹ́ni kò ní gbé inú wọn mọ́.Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

12 Mo bá bèèrè pé, “Ta ni ẹni tí ó gbọ́n, tí òye nǹkan yìí yé? Ta ni OLUWA ti bá sọ̀rọ̀, kí ó kéde rẹ̀? Kí ló dé tí ilẹ̀ náà fi parun, tí ó sì dàbí aṣálẹ̀ tóbẹ́ẹ̀, tí ẹnikẹ́ni kò fi gba ibẹ̀ kọjá?”

13 OLUWA bá dáhùn, ó ní, “Nítorí pé wọ́n kọ òfin tí mo gbékalẹ̀ fún wọn sílẹ̀, wọn kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, wọn kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi,

14 ṣugbọn wọ́n ń fi agídí ṣe ìfẹ́ ọkàn wọn, wọ́n ń bọ àwọn oriṣa Baali, bí àwọn baba wọn ti kọ́ wọn.

15 Nítorí náà, n óo fún wọn ní igi tí ó korò jẹ, n óo sì fún wọn ní omi tí ó ní májèlé mu. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

16 N óo fọ́n wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn ati àwọn baba ńlá wọn kò mọ̀, n óo sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá yọ idà tẹ̀lé wọn títí tí n óo fi pa wọ́n run.”