5 Olukuluku ń tan ọ̀rẹ́ rẹ̀ jẹ,kò sì sí ẹnìkan tí ń sọ òtítọ́.Wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn ní irọ́ pípa;wọ́n dẹ́ṣẹ̀ títí, ó sú wọn,wọn kò sì ronú àtipàwàdà.
6 Ìninilára ń gorí ìninilára,ẹ̀tàn ń gorí ẹ̀tàn,OLUWA ní, “Wọ́n kọ̀ wọn kò mọ̀ mí.”
7 Nítorí náà, ó ní:“Wò ó! N óo fọ̀ wọ́n mọ́,n óo dán wọn wò.Àbí, kí ni kí n tún ṣe fún àwọn eniyan yìí?
8 Ahọ́n wọn dàbí ọfà apanirun,wọ́n ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.Olukuluku ń sọ̀rọ̀ alaafia jáde lẹ́nu fún aládùúgbò rẹ̀,ṣugbọn ète ikú ni ó ń pa sí i ninu ọkàn rẹ̀.
9 Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi?Àbí n kò ní gbẹ̀san ara mi lára irú orílẹ̀-èdè yìí?”
10 Mo ní, “Gbé ẹnu sókè kí o sọkún nítorí àwọn òkè ńlá,sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn nítorí àwọn pápá inú aṣálẹ̀,nítorí gbogbo wọn ti di ahoro, láìsí ẹnìkan tí yóo la ààrin wọn kọjá.A kò ní gbọ́ ohùn ẹran ọ̀sìn níbẹ̀.Ati ẹyẹ, ati ẹranko, gbogbo wọn ti sá lọ.”
11 OLUWA ní, “N óo sọ Jerusalẹmu di àlàpà ati ibùgbé ajáko.N óo sọ àwọn ìlú Juda di ahoroẹnikẹ́ni kò ní gbé inú wọn mọ́.Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”