Jeremáyà 13:12-18 BMY

12 “Sọ fún wọn, ‘Èyí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí: Gbogbo ìgò ni à ó fi ọtí wáìnì kún.’ Bí wọ́n bá sì sọ fún ọ pé, ‘Ṣé a kò mọ̀ pé gbogbo ìgò ni ó yẹ láti bu ọtí wáìnì kún?’

13 Nítorí náà sọ fún wọn pé, ‘èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò fi ìmutípara kún gbogbo olùgbé ilẹ̀ yìí pẹ̀lú Ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì, àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì gbogbo àwọn tó ń gbé ní Jérúsálẹ́mù.

14 Èmi yóò ti èkínní lu èkejì, àwọn baba àti ọmọkùnrin pọ̀ ni Olúwa wí: Èmi kì yóò dáríjìn, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú, èmi kì yóò ṣe ìyọ́nú láti má a pa wọ́n run.’ ”

15 Gbọ́ kí o sì fetísílẹ̀,ẹ má ṣe gbéraga,nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀.

16 Ẹ fi ògo fún Olúwa Ọlọ́run yín,kí ó tó mú òkùnkùn wá,àti kí ó tó mú ẹsẹ̀ yín tàsélórí òkè tí ó ṣókùnkùn,Nígbà tí ẹ̀yin sì ń retí ìmọ́lẹ̀,òun yóò sọ ọ́ di òjìji yóò si ṣe bi òkùnkùn biribiri.

17 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fetísílẹ̀,Èmi yóò sunkún ní ìkọ̀kọ̀nítorí ìgbéraga yín;Ojú mi yóò sun ẹkún kíkorò,tí omi ẹkún, yóò sì máa ṣàn jáde,nítorí a kó agbo Olúwa lọ ìgbèkùn.

18 Sọ fún Ọba àti ayaba pé,“Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀,ẹ sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ yín,adé ògo yín bọ́ sí ilẹ̀ láti orí yín.”