22 Ṣùgbọ́n ìbáṣepọ̀ wọn dúró nínú ìgbìmọ̀ mi,wọn ì bá ti kéde ọ̀rọ̀ mi fún àwọn ènìyàn mi.Wọn ì bá ti wàásù ọ̀rọ̀ mi sí àwọn ènìyànwọn ìbá ti yípadà kúrò nínú ọ̀nààti ìṣe búburú wọn.
23 “Ǹjẹ́ Ọlọ́run tòsí nìkan ni Èmi bí?”ni Olúwa wí,“kì í sì í ṣe Ọlọ́run ọ̀nà jínjìn.
24 Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè sá pamọ́ sí ibi kọ́lọ́fín kan,kí èmi má ba a rí?”ni Olúwa wí.“Ǹjẹ́ èmi kò há a kún ọ̀run àti ayé bí?”ni Olúwa wí.
25 “Mo ti gbọ gbogbo ohun tí àwọn wòlíì èké tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ mi ń sọ. Wọ́n sọ wí pé, ‘Mo lá àlá! Mo lá àlá!’
26 Títí di ìgbà wo ni èyí yóò fi máa tẹ̀ṣíwájú ni ọkàn àwọn wòlíì èké wọ̀nyí tí wọ́n ń sọ ìtànjẹ ọkàn wọn?
27 Wọ́n rò wí pé àlá tí wọ́n ń sọ fún ara wọn yóò mú kí àwọn ènìyàn mi gbàgbé orúkọ mi, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe gbàgbé orúkọ mi nípa sísin òrìṣà Báálì.
28 Jẹ́ kí wòlíì tí ó bá lá àlá sọ àlá rẹ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó ní ọ̀rọ̀ mí sọ ọ́ ní òtítọ́. Kí ni koríko gbígbẹ ní í ṣe nínú ọkà?” ni Olúwa wí.