25 “Mo ti gbọ gbogbo ohun tí àwọn wòlíì èké tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ mi ń sọ. Wọ́n sọ wí pé, ‘Mo lá àlá! Mo lá àlá!’
26 Títí di ìgbà wo ni èyí yóò fi máa tẹ̀ṣíwájú ni ọkàn àwọn wòlíì èké wọ̀nyí tí wọ́n ń sọ ìtànjẹ ọkàn wọn?
27 Wọ́n rò wí pé àlá tí wọ́n ń sọ fún ara wọn yóò mú kí àwọn ènìyàn mi gbàgbé orúkọ mi, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe gbàgbé orúkọ mi nípa sísin òrìṣà Báálì.
28 Jẹ́ kí wòlíì tí ó bá lá àlá sọ àlá rẹ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó ní ọ̀rọ̀ mí sọ ọ́ ní òtítọ́. Kí ni koríko gbígbẹ ní í ṣe nínú ọkà?” ni Olúwa wí.
29 “Ọ̀rọ̀ mi kò há a dàbí iná?” ni Olúwa wí, “àti bí òòlù irin tí ń fọ́ àpáta túútúú?
30 “Nítorí náà, èmi lòdì sí àwọn wòlíì ni,” Olúwa wí, “Tí ń jí ọ̀rọ̀ tí ó yẹ kí ó ti ọ̀dọ̀ mi wá lò lọ́dọ̀ ara wọn.
31 Bẹ́ẹ̀,” ni Olúwa wí, “Èmi lòdì sí àwọn wòlíì tí wọ́n lo ahọ́n wọn káàkiri, síbẹ̀ tí wọ́n ń ṣọ wí pé, ‘Olúwa wí.’