23 Nítorí wọ́n ti ṣe ibi ní ilé Ísírẹ́lì, wọ́n ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn ìyàwó aládùúgbò wọn, àti ní orúkọ mi ni wọ́n ti ṣe èké, èyí tí èmi kò rán wọn láti ṣe. Ṣùgbọ́n, Èmi mọ àwọn nǹkan wọ̀nyí, mo sì jẹ́ ẹlẹ́rìí sí i,” ni Olúwa wí.
24 Wí fún Ṣemáyà tí í ṣe Neelamíyà pé,
25 “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run alágbára Ísírẹ́lì wí: Ìwọ fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ènìyàn ní Jérúsálẹ́mù sí Sefanáyà ọmọ Mááséà tí í ṣe àlùfáà ní orúkọ mi; ó sì sọ fún Sefanáyà wí pé,
26 ‘Olúwa ti yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà rọ́pò Jéhóíádà láti máa jẹ́ alákóso ilé Olúwa, kí o máa fi èyíkéyìí nínú àwọn aṣiwèrè tó bá ṣe bí i wòlíì si inú àgò irin.
27 Nítorí náà, èéṣe tí o kò fi bá Jeremáyà ará Ánátótì wí. Ẹni tí ó ń dúró bí i wòlíì láàrin yín?
28 Ó ti rán iṣẹ́ yìí sí wa ni Bábílónì wí pé, àtìpó náà yóò pẹ́ kí ó tó parí, nítorí náà, ẹ kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé ibẹ̀, ẹ dá oko, kí ẹ sì máa jẹ èṣo ohun ọ̀gbìn oko yín.’ ”
29 Sefanáyà àlùfáà ka lẹ́tà náà sí etí ìgbọ́ Jérúsálẹ́mù tí í ṣe wòlíì.