Jeremáyà 30:11-17 BMY

11 Èmi wà pẹ̀lú rẹ, n ó sì gbà ọ́,’ni Olúwa wí.‘Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀ èdè run,nínú èyí tí mo ti fọ́n ọn yín ká,síbẹ̀ èmi kì yóò pa yín run pátapáta.Èmi yóò bá yín wí pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo nìkan;Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìjìyà.’

12 “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“ ‘Ọgbẹ́ yín kò gbóògùn,bẹ́ẹ̀ ni egbò yín kọjá ìwòsàn.

13 Kò sí ẹnìkan tí yóò bẹ̀bẹ̀ fún àìṣedéédéé yín,kò sí ètùtù fún ọgbẹ́ yín,a kò sì mú yín láradá.

14 Gbogbo àwọn ìbátan yín ló ti gbàgbé yín,wọn kò sì náání yín mọ́ pẹ̀lú.Mo ti nà yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀ta yín yóò ti nà yínmo sì bá a yín wí gẹ́gẹ́ bí ìkànítorí tí ẹ̀bi yín pọ̀ púpọ̀,ẹ̀ṣẹ̀ yín kò sì lóǹkà.

15 Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń kígbe nítorí ọgbẹ́ yín,ìrora yín èyí tí kò ní oògùn?Nítorí ọ̀pọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ẹ̀bi yín tó gani mo fi ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí i yín.

16 “ ‘Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe yín ní ibi ni ibi yóò bá,àní gbogbo àwọn ọ̀ta yín ni a ó sọ di àtìpó ní ilẹ̀ àjòjì;gbogbo àwọn tí wọ́n bà yín jẹ́ ni a ó bàjẹ́.

17 Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìlera fún yín,n ó sì wo ọ̀gbẹ́ yín sàn,’ni Olúwa wí,‘nítorí tí a pè yín ní alárìnkiriSíónì tí gbogbo ènìyàn dágunlá sí.’