21 “Gbé àmì ojú ọ̀nà dìde,ṣe atọ́nà àmì,kíyèsí pópónà rélùwéèojú ọ̀nà tí ó ń gbà.Yípadà ìwọ wúndíá Ísírẹ́lì,padà sí àwọn ìlú rẹ.
22 Ìwọ yóò ti sìnà pẹ́ tó,ìwọ aláìsòótọ́ ọmọbìnrin; Olúwa yóò dá ohun tuntun lórí ilẹ̀,ọmọbìnrin yóò yí ọkùnrin kan ká.”
23 Báyìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì wí: “Nígbà tí èmi bá kó wọn dé láti ìgbèkùn; àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Júdà àti ní àwọn ìlú rẹ̀ yóò tún lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí lẹ́ẹ̀kan síi; wí pé, ‘Olúwa bùkún fún ọ, ìwọ tí ń gbé nínú òdodo, ìwọ òkè ìwà mímọ́.’
24 Àwọn ènìyàn yóò gbé papọ̀ ní Júdà àti ní gbogbo àwọn ìlú rẹ̀; bákan náà ni àgbẹ̀ àti àwọn tí ń tẹ̀lé agbo ẹran wọn ká.
25 Èmi yóò sọ aláàárẹ̀ di ọ̀tun, èmi yóò sì tẹ́ gbogbo ọkàn tí ń káànú lọ́rùn.”
26 Lórí èyí ni mo jí, mo sì wò yíká, oorun mi sì dùn mọ́ mi.
27 “Wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “nígbà tí èmi yóò gbin ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà pẹ̀lú irúgbìn ọmọ ènìyàn àti ẹranko.