24 Àwọn ènìyàn yóò gbé papọ̀ ní Júdà àti ní gbogbo àwọn ìlú rẹ̀; bákan náà ni àgbẹ̀ àti àwọn tí ń tẹ̀lé agbo ẹran wọn ká.
25 Èmi yóò sọ aláàárẹ̀ di ọ̀tun, èmi yóò sì tẹ́ gbogbo ọkàn tí ń káànú lọ́rùn.”
26 Lórí èyí ni mo jí, mo sì wò yíká, oorun mi sì dùn mọ́ mi.
27 “Wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “nígbà tí èmi yóò gbin ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà pẹ̀lú irúgbìn ọmọ ènìyàn àti ẹranko.
28 Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń ṣọ́ wọn, láti fàtu, àti láti wó lulẹ̀, àti láti gba ìṣàkóso, láti bàjẹ́ àti láti mú ibi wá, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣọ́ wọn láti kọ́ àti láti gbìn,” ni Olúwa wí.
29 “Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ènìyàn kò ní sọ mọ́ pé:“ ‘Àwọn baba ti jẹ èṣo kíkanàti pé ẹyín kan àwọn ọmọdé.’
30 Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ èṣo kíkan ni eyín yóò kan.