1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá nípa àwọn Júù tí ń gbé ní ìsàlẹ̀ Éjíbítì ní Mígídò, Táfánásì àti Mémífísì àti ní apá òkè Íjíbìtì:
2 “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Wo ibi tí mo mú bá Jérúsálẹ́mù àti gbogbo ìlú Júdà. Lónìí, wọ́n wà ní ìyapa àti ìparun.
3 Nítorí pé ibi tí wọ́n ti ṣe. Wọ́n mú mi bínú nípa tùràrí fínfín àti nípa bíbọ àwọn òrìṣà, yálà èyí tí ìwọ tàbí àwọn baba rẹ kò mọ̀.
4 Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní mo rán wòlíì mi, èyí tí ó wí báyìí pé, ‘Má ṣe àwọn ohun búburú tí èmi kò fẹ́.’
5 Ṣùgbọ́n wọn kò fetísílẹ̀ láti fi ọkàn si. Wọn kò sì yípadà kúrò nínú búburú wọn tàbí dáwọ́ ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà dúró.
6 Fún ìdí èyí, ìbínú gbígbóná mi ni èmi yóò yọ sí àwọn ìlú Júdà àti òpópó Jérúsálẹ́mù àti sísọ wọ́n di ìparun bí ó ṣe wà lónìí yìí.
7 “Báyìí tún ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì wí: Kí ló dé tí ẹ fi ń mu ibi ńlá yìí wá sí orí ara yín nípa yíyapa kúrò lára Júdà ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti èwe, tí ẹ kò sì ku ọ̀kankan?