Jeremáyà 44:24-30 BMY

24 Nígbà náà ni Jeremáyà dáhùn pẹ̀lú obìnrin náà pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ọmọ Júdà tí ó wà ní Éjíbítì.

25 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Ìwọ àti àwọn Ìyàwó rẹ fihàn pẹ̀lú àwọn ìhùwà rẹ àti àwọn ohun tí ó ṣèlérí nígbà tí o wí pé, ‘Àwa yóò mú ẹ̀jẹ́ tí a jẹ́ lórí sísun tùràrí àti dída ọtí sí orí ère ayaba ọ̀run ṣẹ.’“Tẹ̀ṣíwájú nígbà náà, ṣe ohun tí o sọ, kí o sì mú ẹ̀jẹ́ rẹ ṣẹ.

26 Ṣùgbọ́n gbọ ọ̀rọ̀ Olúwa, gbogbo ẹ̀yin Júù tí ń gbé ilẹ̀ Éjíbítì, mo gégùn-ún: ‘Mo búra pẹ̀lú títóbi orúkọ mi,’ bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, ‘wí pé, kò sí ẹnikẹ́ni láti Júdà tí ń gbé ibikíbi ní Éjíbítì ni tí ó gbọdọ̀ ké pe orúkọ mi tàbí búra. “Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó dá wa ti wà láàyè.”

27 Nítorí náà, mò ń wò wọ́n bí i fún ìparun, kì í ṣe fún rere. Àwọn Júù tí ó wà ní Éjíbítì yóò parun pẹ̀lú idà àti ìyàn títí tí gbogbo wọn yóò fi parun.

28 Àwọn tí ó bá sá àsálà kúrò lọ́wọ́ ìparun idà àti pípadà sí ilẹ̀ Júdà láti Éjíbítì yóò kéré níye. Gbogbo àwọn tí ó bá kú ní ilẹ̀ Júdà, tí ó wá gbé ilẹ̀ Éjíbítì yóò mọ ọ̀rọ̀ ẹni tí yóò dúró yálà tèmi tàbí ti yín.

29 “ ‘Èyí ni yóò jẹ́ àmì fún un yín pé èmi yóò fi ìyà jẹ yín níbi tí Olúwa ti sọ láti lè jẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ìjìyà mi tí mo sọ pé ẹ̀ ó jẹ yóò ṣẹ.’

30 Báyìí ni Olúwa wí: ‘Èmi yóò fi Fáráò Hópírà Ọba Éjíbítì lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́, èyí tí ó lè pa ayé rẹ́; gẹ́gẹ́ bí mo ti fi Sedekáyà Ọba Júdà lé Nebukadinésárì Ọba Bábílónì lọ́wọ́ ọ̀tá tó ń lépa ẹ̀mí rẹ̀.’ ”