1 Ṣédékáyà jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó jẹ Ọba. Ọdún mọ́kànlá ló fi jọba ní Jérúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hámútalì ọmọ Jeremáyà; láti Líbíná ló ti wá.
2 Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa gẹ́gẹ́ bí Jéhóáikímù ti ṣe
3 Nítorí ìbínú Olúwa ni gbogbo èyí ṣe ṣẹlẹ̀ sí Jérúsálẹ́mù àti Júdà àti ní ìkẹyìn. Ó sì gbà wọ́n gbọ́ ní iwájú rẹ̀. Sedekáyà ṣọ̀tẹ̀ sí Ọba Bábílónì.
4 Nígbà tí ó di ọdún kẹ́sàn án ti Sedekáyà tí ń ṣe ìjọba ní ọjọ́ kẹ́wàá, oṣù kẹ́wàá Nebukadinésárì Ọba Bábílónì sì lọ sí Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n pàgọ́ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà; wọ́n sì mọ odi yíká rẹ̀.
5 Ìlú náà sì wá lábẹ́ ìhámọ́ títí di ọdún kọkànlá Ọba Sédékáyà.