3 Níbikíbi tí mo bá lé wọn lọ, gbogbo àwọn ìyókù wọn yóò fẹ́ ikú ju ìyè lọ ni Olúwa Àwọn ọmọ ogun wí.’
4 “Wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“ ‘Bí ènìyàn bá ṣubú lulẹ̀wọn kì í padà dìde bí? Nígbà tíènìyàn bá yà kúrò ní ọ̀nà rẹ,kì í yí padà bí?
5 È é ṣe nígbà náà àwọn ènìyàn wọ̀nyífi yà kúrò lọ́nà rẹ̀? Kílódé tí Jérúsálẹ́mùfi yà kúrò ní gbogbo ìgbà?Wọ́n rọ̀ mọ́ ẹ̀tàn, wọ́n kọ̀ láti yípadà.
6 Mo ti fetí sílẹ̀ dáradára, wọnkò sọ ohun tí ó tọ́. Kò sí ẹnìkan tóronúpìwàdà nínú ìwà búburú rẹ̀,kí ó wí pé, “Kí ni mo ṣe?” Olúkúlùkùń tọ ọ̀nà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹṣin tó ń lọ sójú ogun.
7 Kódà, ẹyẹ àkọ̀ ojú ọ̀run mọ ìgbàtirẹ̀, àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀ àti lékèélékèémọ àkókò ìsípòpadà wọn. Ṣùgbọ́n àwọnènìyàn mi kò mọ ohun tí Ọlọ́run wọn fẹ́.
8 “ ‘Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè wí pé, “Àwa gbọ́n,nítorí a ní òfin Olúwa,” nígbàtí ó jẹ́ pé kálámù èké àwọnakọ̀wé ti àwọn sọ ọ́ di ẹ̀tàn
9 Ojú yóò ti àwọn ọlọ́gbọ́n, a ó dàwọ́n láàmú, wọn yóò sì kó sí ìgbèkùn.Nítorí wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa. Irú ọgbọ́nwo ló kù tí wọ́n ní?